ỌPẸ O! SHAN GEORGE NAA TI PADE OLOLUFẸ TUNTUN LẸYIN TO PE AADỌTA ỌDUN LAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 11, 2020

ỌPẸ O! SHAN GEORGE NAA TI PADE OLOLUFẸ TUNTUN LẸYIN TO PE AADỌTA ỌDUN LAYE


Ṣẹnkẹn bayii ni inu gbajugbaja oṣere tiata nni, Shan George n dun bayii lori bo ṣe pade ololufẹ tuntun ti igbagbọ rẹ wa pe wọn yoo ba ara wọn kalẹ. 

Funra oṣerebinrin naa lo gbe fọto ara rẹ pẹlu oruka ifẹ ti ololufẹ tuntun naa ṣẹṣẹ fun un sori ikanni ayelujara ti Istagiraamu l'Ọjọru ti i ṣe Wẹside ijẹta, nibi to ti n ni k'awọn eeyan maa ba oun dupẹ pe oun naa ti kuro lagboole awọn iya-n-dagbe. 

Shan ninu ọrọ to kọ s'abẹ fọto rẹ to gbe sita lo ti fi ye gbogbo eeyan pe ipinlẹ Cross Rivers t'oun ti wa naa ni ololufẹ oun naa ti wa, t'awọn si nifẹẹ ara wọn denudenu.

Bakan naa lo tun kọ ọ sibẹ pe ko ti i pẹ ju f'oun lati ni ọkọ miran, to si tun n fi igbagbọ kun un wi pe awọn yoo ba ara wọn kalẹ.

 

F'awọn to ba mọ Shan daadaa, wọn yoo mọ pe ẹẹmẹta ọtọọtọ lo ti ṣe igbeyawo t'awọn igbeyawo naa si daru pẹlu b'oun at'awọn ọkọ rẹ tẹlẹ naa ṣe ja iwe funra wọn, tonikaluku si ba tirẹ lọ.

Iya arugbo ẹni aadọta ọdun ni Shan, to si ti ni awọn ọmọ-ọmọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI