Idunnu nla lo ṣubu lu ayọ awọn ara ipinlẹ Rivers n'igba ti wọn pe gbajugbaja ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to ti n da wọn laamu lati bi ọdun meloo kan sẹyin ti jade laye lẹyin ikọlu oun pẹlu awọn ọlọpaa.
Honest Digbara t'ọpọ awọn eeyan mọ si Bọbisky lorukọ ẹ, ti a si gbọ pe o ti pẹ t'awọn ọlọpaa ti n wa a, koda, ti wọn ni Gomina wọn, Nyesom Wike naa tun gbe miliọnu lọna ọgbọ naira silẹ fẹnikẹni to ba ri Bọbisky mu.
Nigba tọwọ maa tẹ ẹ, a gbọ pe ṣe doju ija kọ awọn ọlọpaa loru Satide ọsẹ to kọja yii, ṣugbọn ti wọn pada gba agbara lọwọ ẹ ni tipatipa.
Bi iroyin naa ṣe jade sita l'awọn araalu ti dana ariya rẹpẹtẹ, ti wọn si n kọrin ọpẹ si Ọlọrun.
No comments:
Post a Comment