Lonii ni idunnu tun ṣubu lu ayọ awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara n'igba ti ijọba ipinlẹ naa fun awọn ọba mẹfa niwee ati ọpa aṣẹ lati maa ṣakoso awọn agbegbe ti wọn j'ọba si i.
Awọn ọba naa ti wọn wa nipo kẹta (3rd Class) ati ikẹrin (4th Class) lawujọ awọn ọba alade la gbọ pe ijọba ipinlẹ labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fi ontẹ lu pe wọn yege pẹlu b'awọn araalu ṣe fa wọn kalẹ wi pe awọn ni ipo naa tọ si.
AWIKONKO gbọ pe igbimọ awọn afọbajẹ nípinlẹ naa tun bu ọwọ lu awọn ọba tuntun yii wi pe wọn yege fun awọn ipo naa.
Lara awọn ọba naa ni: Ọba Ezekiel Ajibọla Ọmọbanjọ, Oloke tilu Oke-Opin n'ijọba ibilẹ Ekiti; Ọba Abdulwahab Bọlaji Usman, Onimosudo tilu Masudo; Ọba Simeon Ibiyinka Ọlaonipẹkun, Ọba tilu Afin Ile-Ire ati Ọba Moses Ademọla
Adeṣhina, Aṣaoro tilu Alaṣaro ti wọn wa n'ijọba ibilẹ Ifẹlodun.
Awọn yooku ni Ọba Abdulwahab Aboyeji Ayanda Ogunbiyi, Eleku tilu Odo-Eku n'ijọba ibilẹ Isin; Ọba Ganiyu Toyin Ọlanrewaju toun jẹ Oninaja tilu Inaja Alaro n'ijọba ibilẹ Oyun.
N'igba to n gbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri fun wọn, Kọmiṣanna fun eto oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe, Aliyu Mohammed Saifudeen gb'awọn lamọran jẹ awokọṣe f'awọn araalu ti wọn fẹẹ sin, ki wọn si fi ifẹ ati iṣọkan b'awọn eeyan lo.
No comments:
Post a Comment