Bi wọn ṣe mu ayederu Jesu ti wọn pe orukọ rẹ ni Sergei Torop ko fẹẹ yatọ si bi wọn ṣe mu ojulowo Jesu ọmọ Josẹfu ninu bibeli pẹlu bi wọn ṣe l'awọn ọlọpaa at'awọn ologun ṣe digun lọ sile ẹ.
Gbajugbaja ni wọn pe Sergie ti inagijẹ rẹ n jẹ Vissarion, koda wọn ni ogbologbo olori ọmọ ẹgbẹ okunkun ti orilẹ-ede Russia ni. Ilu Siberia la gbọ pe ọwọ palaba Sergie ti segi laarọ ọjọ Iṣẹgun, Tuside to kọja yii, iyẹn ọjọ kejilelogun oṣu yii.
A gbọ pe ṣe l'awọn ọlọpaa at'awọn ọtẹlẹmuyẹ ti orilẹ-ede Russia, eyi ti wọn pe ni Russian troops yabo ibi ti wọn ti gburo rẹ pẹlu awọn nnkan ija ogun, tọwọ si tẹ oun ati amugbalẹgbẹ rẹ, Vadim Redkin.
Gbajumọ olorin takasufee ni wọn pe Vadim to jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Sergie, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59).
Gbajumọ olorin takasufee ni wọn pe Vadim to jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Sergie, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59).
Ohun ti wọn ni Sergie to jẹ ajagunfẹyinti ati ọlọpaa to n dari ọkọ oju popona tẹlẹri maa n sọ kiri ni pe ọdun 1990 ni wọn tun oun bi gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, eyi ti Jesu ṣeleri rẹ ki wọn to o kan an mọ agbelebu.
No comments:
Post a Comment