Fathia ati oku e
Gbo gbo ilu Abẹokuta lo mi titi l'ọjọ Ẹti, Fraide ọsẹ to kọja yii nigba ti wọn ri oku ọmọdebinrin, kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Fathia Moyọsọrẹ Ọjẹwọle ninu ile akọku nibi ti wọn ti f'ipa ba a laṣepọ to fi jẹ ipẹ Ọlọrun.
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe ni nnkan bi aago meje aabọ alẹ Ọjọru, iyẹn Wẹside ọsẹ to kọja yii la gbọ pe mama Fathia, iyẹn Arabinrin Yetunde Ọjẹwọle ran ọmọ naa n'iṣẹ lati lọ ra afẹfẹ gaasi ti wọn yoo fi dana wa.
Latigba naa la gbọ pe wọn ko ti ri Fathia ti wọn l'ọmọ ọdun mẹrinla ni naa mọ, ṣugbọn ti wọn pada ri oku ẹ ninu ile akọku kan to wa ladugbo Oriyanrin, Agbẹlọba n'ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun nitosi ibi ti wọn n gbe.
Gẹgẹ b'awọn to f'iṣẹlẹ naa to AWIKONKO lọwọ fi ṣe ye wa, a gbọ pe bi Fathia se gbe afẹfẹ gaasi naa pada, oun pẹlu ọkunrin kan ti wọn lo o wọ aṣọ funfun ni, ti kọ si ba ẹnikẹni sọrọ nigba to dele, ko to tun tẹlẹ ẹni naa pada.
Gbogbo bi wọn ṣe n pe Fathia ti wọn tun n pe ni Moyọsọrẹ ni ko dahun, to ni ki wọn f'oun silẹ, to si ba ẹni naa lọ, idi ree ti wọn fi lo ṣeeṣe ko jẹ pe ṣe l'ọkunrin naa f'oogun ba a sọrọ.
Alọ ọmọ yii ni wọn ri, ko sẹni to mọ apadabọ ẹ, ti a si gbọ pe tilẹ ọjọ naa fi ṣu, to fi mọ ni iya rẹ ko sun. Loju ẹsẹ si la gbọ pe Yetunde to jẹ iya ọmọ yii ti ranṣẹ pe baba Fathia toun n gbe nilu Eko lati fi to o leti.
Awọn ọlọpaa naa gbọ si ọrọ yii, ṣugbọn ti wọn jẹ ko ye awọn to lọ sọdọ wọn wi pe awọn ko le bẹrẹ iwadii, afi to ba pe wakati mẹrinlelogun gbako. Si iyalẹnu, nigba ti wọn maa pada ri oku Fathia, inu ile akọku kan ni wọn ti ri i nihoho ọmọluabi, iyẹn nibi ti wọn fipa ba a laṣepọ si to fi ku.
Ni bayii, alukoro awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ti ṣalaye pe iwadii awọn ti bẹrẹ lati mọ ẹni to pa Fathia danu sinu ile akọku naa, to si l'awọn nigbagbọ pe ọwọ yoo tẹ ẹni naa laipẹ.
No comments:
Post a Comment