Inu idunnu ati ayọ ni gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọlaniyan Yussuf at'awọn ẹbi rẹ wa bayii lori bi Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ṣeleri wi pe oun yoo ran an nile ẹkọ , nibi ti yoo ti gba oye Masters rẹ.
Akẹkọọ to dara julọ ni fasiti tilu Ilọrin, iyẹn University of Ilorin ni wọn pe Yussuf ti Gomina fẹẹ ran nile ẹkọ fasiti Nothingham to wa ni England, London.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni nigba ti Gomina AbdulRazaq gburo nipa ọmọkunrin naa lo ti sọ pe oun yoo ran an lọwọ lori eto ẹkọ rẹ, nitori pe iwuri nla lo jẹ fun ipinlẹ naa lati ni iru awọn eeyan bi i tiẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni nigba ti Gomina AbdulRazaq gburo nipa ọmọkunrin naa lo ti sọ pe oun yoo ran an lọwọ lori eto ẹkọ rẹ, nitori pe iwuri nla lo jẹ fun ipinlẹ naa lati ni iru awọn eeyan bi i tiẹ.
No comments:
Post a Comment