AWỌN ILERI MI L'ASIKO IPOLONGO IBO ṢI F'ẸSẸ MULẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 27, 2020

AWỌN ILERI MI L'ASIKO IPOLONGO IBO ṢI F'ẸSẸ MULẸ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ko si nnkan to le yi awọn ileri oun lasiko ipolongo idibo, paapaa awọn ileri nipa ijọba ibilẹ pada, nitori pe ijọba ibilẹ yoo da duro ni gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin.
 
Ni nnkan bi oṣu meloo kan ṣeyin l'awọn nnkan gbe iroyin kiri pe ijọba ipinlẹ naa gba owo ti ko din ni miliọnu lọna ọọdunrun ninu owo ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ naa laaarin ọdun ọdun to kọja si ọdun yii.
 
Eyii lo mu k'ijọba yan awọn igbimọ iwadii lati mọ ibi t'awọn owo naa n gba, ti ijọba si ṣeleri lati f'iya jẹ awọn ti ọrọ naa ṣi mọ lori.
 
Igbimọ naa la gbọ pe wọn ṣẹṣẹ pari iwadii wọn, ti wọn si l'awọn ko ri ipa kankan to fídi rẹ mulẹ pe ijọba ipinlẹ yọ ninu owo ijọba ibilẹ, iyẹn awọn owo to n wa lati ọdọ ijọba apapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI