AWỌN AJAGUNGBALẸ YAWỌ ILU KẸLẸMBẸRI, NI WỌN BA N KE SI IJỌBA IPINLẸ OGUN FUN IRANLỌWỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 6, 2020

AWỌN AJAGUNGBALẸ YAWỌ ILU KẸLẸMBẸRI, NI WỌN BA N KE SI IJỌBA IPINLẸ OGUN FUN IRANLỌWỌ


Asiko yii ki i ṣe asiko to dun rara fun gbogbo awọn ọmọ bibi ati olugbe ilu kan ti wọn n pe ni Kẹlẹmbẹri to wa n'itosi Ọbada-Oko, ijọba ibilẹ Ewekero lori bi wọn ṣe l'awọn ajagungbalẹ ṣe wọ ilu naa, ti wọn si bẹrẹ si i gba ilẹ onilẹ, koda, ti wọn tun n ta a f'awọn eeyan.

Orin 'Idowu Fadipẹ ole, Alowonle ole' l'awọn araalu Kẹlẹmbẹri mu sẹnu l'ọjọ Abamẹta ti i ṣe Satide ana n'igba ti wọn n fẹhonu wọn han si b'awọn ajagungbalẹ ṣe ya wọ inu ilu wọn, ti wọn si n sọ awọn eeyan di alainile lori.

Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun; Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun; Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun at'awọn alẹnulọrọ lawujọ l'awọn eeyan naa n ke gbajare si fun iranlọwọ lori aabo ẹmi ati dukia wọn kuro lọwọ awọn ajagungbalẹ naa.


Lati nnkan bi oṣu mẹfa sẹyin la gbọ pe awọn ajagungbalẹ naa ti wọn ni obinrin kan, Idowu Fadipẹ jẹ olori wọn ti wọ inu ilu naa, ti wọn si n dunkooko mọ ẹmi awọn ọmọ onilu lati fipa gba ilẹ lọwọ wọn.

Wọn ni ṣe ni Idowu Fadipẹ naa ko tọọgi rẹpẹtẹ wọ inu ilu pẹlu ibọn ati oriṣiriṣi ohun ija oloro lati fi kọlu awọn eeyan, koda ti wọn ni Baale ilu naa, Oloye Rasheed Adeboun ko to ẹni to n gbe ilu naa mọ lasiko ta a ko iroyin yii jọ.


AWIKONKO gbọ pe Idowu Fadipẹ tun mu ẹni kan to n jẹ Nurudeen Araba, ti wọn tun n pe ni Alowonle, ẹni ti wọn loun n ṣiṣẹ alagbata ilẹ ati dukia wọ ilu naa lati tete ba a ta awọn ilẹ agbegbe naa, ki wọn si pin owo ẹ.

Iyalẹnu nla lo jẹ f'awọn oloye at'awọn agbaagba ilu, to fi mọ awọn ọdọ ilu naa n'igba ti wọn ri nnkan to n ṣẹlẹ, ti wọn si l'awọn ko ni i gba ki wọn f'ọbẹ ẹyin jẹ wọn niṣu, eyi lo jẹ ki wọn lọ koju wọn, lai mọ pe awọn yẹn naa ti mura ogun dani.

Ṣe la gbọ pe awọn tọọgi ti Idowu Fadipẹ ati Nurudeen Araba ko wọle ṣina ibọn bolẹ f'awọn araalu, t'awọn yẹn si na papa bora, latigba naa la gbọ pe awọn araalu ti f'ilu silẹ, ti wọn ko lẹ debẹ mọ.

N'igba ti wọn ri i pe awọn ajagungbalẹ yii ko ṣetan lati kuro nilu wọn lo mu ki wọn gba ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2 to wa nilu Eko lọ lati fi to wọn leti, koda ti wọn tun fọrọ naa to agbẹjọro wọn, Ọgbẹni A. Ogungbade leti, ti agbẹjọro naa si ba wọn kọ iwe ẹbẹ ranṣẹ si abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Kunle Oluọmọ lati gba wọn.

Opin ọsẹ to kọja yii l'awọn araalu ṣe iwọde ifẹhonu han, nibi ti wọn ti n bẹ gbogbo awọn alẹnulọrọ patapata n'ipinlẹ Ogun, paapaa kọmiṣanna ọlọpaa lati dide iranlọwọ si wọn.


Ninu ọrọ rẹ, Oloye Rasheed Adeboun ni "Oṣu kẹrin ọdun yii loun ti de inu ilu toun jẹ baalẹ si gbẹyin nitori b'awọn ajagungbalẹ ṣe n wa oun lati pa danu. O ni wọn ti kọkọo dana iya f'oun nigba kan ri, ti wọn tun fẹẹ ṣa oun pa lagbegbe Adigbẹ, Abẹokuta l'ọsẹ meloo kan sẹyin.

Oloye Rasheed sọ pe ọwọ Ọlọrun ati ijọba ipinlẹ Ogun to fi mọ awọn agbofinro nikan ni ẹmi awọn wa bayii.

Baalẹ ilu Arẹyin, Oloye Ṣobọwale Adekunle Alani ninu ọrọ tirẹ fi ye wa pe gbogbo idile to tẹ ilu naa do l'awọn mọ patapata, to si ni ọmọ ale lasan ni Idowu Fadipẹ jẹ ninu ilu awọn, ati pe ko figba kan ri gbe inu ilu naa, to si lo ya awọn lẹnu nigba to de lojiji pẹlu awọn tọọgi.

O tun sọ ninu ọrọ rẹ siwaju pe gbogbo ipilẹ ile (foundation) t'awọn eeyan ti ṣe sibẹ ni wọn ti fi katakata ti wọn gbe wa woo danu, wi pe afi ki wọn tun ilẹ ra, to si ni awọn baba nla ẹ ko ni ilẹ kankan lagbegbe naa.

Gbogbo awọn araalu ti wọn b'AWIKONKO sọrọ jẹ ko ye wa pe ṣe l'awọn ajagungbalẹ naa tun lo anfaani bi wọn ṣe le awọn kuro n'ilu lati fi ja wọn lole dukia ati ohun ọsin wọn bi ewurẹ, adiẹ, ti wọn si tun ja ṣọọbu ko wọn lẹru.

Wọn ni ojoojumọ l'awọn ajagungbalẹ naa n wa yinbọn lati fi le awọn eeyan danu, ti wọn ni ṣe ni wọn n pariwo pe awọn yoo yinbọn pa ẹnikẹni to ba gbiyanju lati da wọn lọwọ kọ lori awọn ilẹ t'awọn fẹẹ gbẹsẹ le.

N'igba to n tako awọn ẹsun ti wọn fi kan an, Idowu Fadipẹ sọ pe ko si otitọ kankan ninu awọn ẹsun naa nitori pe ọmọ bibi ilu Kẹlẹmbẹri loun, ati pe baba-baba oun wa lara awọn to tẹ ilu naa do n'igba aye ẹ. O loun pẹlu awọn to fa Baalẹ ilu wọn kalẹ l'ọdun diẹ sẹyin, lai mọ pe ṣe ni wọn maa pada fi ibi ṣu oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI