Ileeṣẹ ojulalakanfinṣọri lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, VGN ti pariwo sita wi pe awuyewuye to n lọ kaakiri lasiko yii wi pe awọn oṣiṣẹ wọn fẹẹ ṣe iwọde lati d'awọn eeyan lẹkọọ ki i ṣe lati ọdọ wọn.
Gẹgẹ bi atẹjade ti alukoro ileeṣẹ naa lapapọ, Ọgbẹni Nureni Ọlanrewaju Adedoyin fi ranṣẹ si AWIKONKO lalẹ ana, Mọnde lo ti sọ pe awọn ko lọwọ si iroyin naa ti iroyin ori ayelujara kan gbe sita.
Adedoyin ni ojule kinni, Ibrahim Gambari Crescent, Katampe new extension, Abuja ni olu ileeṣẹ wọn wa, awọn ko si ni igbeṣẹ kankan lati ṣe iwọde kaakiri orilẹ-ede Naijiria lati d'awọn eeyan lẹkọọ lori ọrọ eto aabo.
Ninu atẹjade naa lo tun ti tọka si awọn koko mẹsan-an pataki, eyi to fi n tako iroyin naa wi pe ẹni to gbe iroyin naa sita lo n fi orukọ ọga wọn lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri.
1. Ayederu iroyin nipa wi pe a fẹẹ ṣe iwọde ko jade lati olu ileeṣẹ wa.
2. VGN ko ni erongba lati ṣe iwọde kankan kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa lorilẹ-ede yii lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan-an ọdun 2020.
3. Ọga wa patapata lapapọ fun ẹgbẹ Vigilante Group of Nigeria ni Dọkita Usman Muhammad Jahun fsi.
4. Ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Umar Bakori lo n fi orukọ ọga agba wa lu jibiti, nitori pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ti paṣẹ wi pe Dọkita Usman Muhammad Jahun ni ko jẹ ọga agba patapata fun VGN.
5. VGN ko gbaradi lati ran awọn ọlọpaa tabi oniruuru ileeṣẹ eleto aabo kankan lọwọ. VGN ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu ọlọpaa at'awọn ileeṣẹ eleto aabo toku tipẹtipẹ, t'awọn naa si n gbaruku ti wọn.
6. Gbogbo awọn adari patapata kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji ni wọn ti gba aṣẹ lati fi to kọmiṣanna ọlọpaa, ọga DSS ati ọga Sifu Difẹnsi wọn leti nipa iwọde ti ko lẹsẹ nilẹ naa.
7. Iwọde ko si lara eto ati alakalẹ VGN fun ọdun yii.
8. A n gba gbogbo eeyan lamọran lati ma ṣe tẹwọ gba iwọde naa nitori pe ayederu lasan ni iroyin naa jẹ.
9. Awọn araalu gbọdọ fi to awọn ọlọpaa tabi ileeṣẹ eleto aabo to ba sunmọ wọn leti bi wọn ba kofiri iwọde ita gbangba naa.
lakotan, ọkunrin naa wa a rọ ẹnikẹni to ba ni ibeere tabi alaye lẹkunrẹrẹ lati yọju si olu ileeṣẹ wọn.
No comments:
Post a Comment