'Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀, bí ọyẹ́ tí ń borí oru' ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fẹẹ fi ọ̀rọ̀ náà ṣe pelu bí wọn ṣe fi eto ìpolongo 'Fọ Kwara Mọ', ìyẹn Clean Kwara Campaign lélẹ̀.
Ọjọ́ Aje, Mọnde àná ni ìjọba fi eto naa lélẹ̀ láti lè jẹ ki àlàáfíà àti ìlera pípé jọba káàkiri gbogbo ìgbèríko pátápátá tó wà nipinlẹ náà.
Èyí ni wọn ṣe láti fi saami ayẹyẹ ọdún karùn-ún tí Sustainable Development Goals (SDGs), lèyí tí wọn fi ń fòpin sí báwọn aráàlú ṣe ń yagbẹ kiri ìta gbangba.
Àfojúsùn ìjọba Kwara lórí eto yìí ni lati jẹ ki eto ìlera ṣe pàtàkì soun àti pé bí yóò bá fi di ọdún 2030, kò ní í sì wí pé àwọn èèyàn ń yagbẹ káàkiri ibi tí wọn ba ti rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò tún máa rí omi ẹ̀rọ gidi mú.
AWIKONKO gbọ pé eto yìí tí ń mú ibẹrubojo báwọn kan láàrin ìlú, pàápàá àwọn ilé tí wọn kò ní ṣalanga, nítorí a tijọba tí jẹ kò di mimọ pé àwọn kò níí fi ọwọ yẹpẹrẹ mú eto naa.
No comments:
Post a Comment