PONDEI, AKPABIO TUN WỌ WAHALA TUNTUN L'ỌDỌ EFCC LORI ỌRỌ OWO NDDC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 20, 2020

PONDEI, AKPABIO TUN WỌ WAHALA TUNTUN L'ỌDỌ EFCC LORI ỌRỌ OWO NDDC

Ajọ to n ri si ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti bẹrẹ iwadii lori bi wọn ṣe ṣe owo kan to jẹ ti ileeṣẹ to n ri sọrọ idagbasoke Niger Delta, iyẹn Niger Delta Development Commission, eyi ti wọn lo poora lojiji.

Minisita fọrọ ileeṣẹ NDDC, Godswill Akpabio ati alakoso igbimọ fidihẹ ni ileeṣẹ naa, Ọjọgbọn Kemebradikumo Pondei ni iwadii ti bẹrẹ lori wọn bayii lori bi wọn ṣe ṣe awọn owo to wa fun ileeṣẹ naa.

Ẹgbẹ ajọ araalu kan ti wọn pe ni Foundation for True Freedom and Good Governance, ti Ajafẹtọ Deji Adeyanju n dari rẹ ni wọn dabaa pe ki iwadii bẹrẹ lori bi wọn ṣe na owo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI