ỌDÚN HIJRAH: GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'AWỌN MÙSÙLÙMÍ ṢAJỌYỌ, BẸ́Ẹ̀ LO TÚN GBÀDÚRÀ ŃLÁ FÚN WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 21, 2020

ỌDÚN HIJRAH: GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ B'AWỌN MÙSÙLÙMÍ ṢAJỌYỌ, BẸ́Ẹ̀ LO TÚN GBÀDÚRÀ ŃLÁ FÚN WỌN


Bí gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí káàkiri àgbáyé ṣe ń ṣe ajọyọ ayẹyẹ onka ọdún tuntun ti Hijrah 1442, Gómìnà ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí fi àdúrà ranṣẹ sì wọn pé 'Pẹ̀lú ògo Ọlọhun lẹ máa ṣe pupọ rẹ láyé'.

Gómìnà AbdulRazaq tún gbàdúrà pé ọdún náà 1442 AH yóò mú irọrun àti òpin sí ajakalẹ àrùn COVID-19 tó so gbogbo àgbáyé mọ inú ìgbèkùn.

Ṣáájú àsìkò yìí ni ẹgbẹ́ tó ń ṣàkóso ẹsin Isilaamu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA) tí kéde ọjọ́ Ẹti, Fraide òní láti fi sàmì ọdún tí Annọbi Muhammad kúrò láti Mẹka lọ sí Mẹdina. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI