Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti rọ gbogbo awọn araalu, paapaa awọn olugbe agbegbe Ọyọ Avenue to wa ni Olorin, ilu Adiyan n'ijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun wi pe ti wọn ba kofiri alaboyun kan to loyun tẹlẹ, to si ti bimọ, ṣugbọn ti wọn ko ri ọmọ lẹyin ẹ lati tete fi to wọn leti.
Idi ni pe ọmọ kan ni wọn ri ninu ṣalanga l'ọjọ Satide, Abamẹta anaa lagbegbe naa, ti wọn ko si mọ bo ṣe debẹ.
AWIKONKO gbọ pe ọmọ oojọ ni ọmọ naa ti wọn ba ninu ṣalanga yii nihoho ọmọluabi, ti wọn si ti i ri ẹni to juu sibẹ titi ti a fi kọ iroyin yii tan.
Epe nla-nla n pe ara wọn ran n'iṣẹ n'igba ti ariwo ọmọ yii gba gbogbo agbegbe naa kan, ko to o di pe wọn lọ ranṣẹ s'awọn ọlọpaa agbegbe Agbado lati wa a woran kayeefi naa.
Pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpaa ni wọn fi gbe ọmọ naa lọ si ọsibitu agbegbe to wa ni Oke-Aro, nibi ti wọn ti n tọju rẹ lọwọ, ti a si gbọ pe bi wọn ba t'ọju rẹ tan, ile awọn ọmọ alailobii ni wọn maa gbe e lọ fun itọju to pe ye.
AWIKONKO gbọ pe awọn ọmọ kekeeke ti wọn n ṣere lẹgbẹ ṣalanga yii ni wọn gbọ ẹkun ọmọ naa, ti wọn si ro pe adiẹ lo jabọ sibẹ, to mu ki wọn lọ pe iya agba kan toun wa layika.
Iya agba naa lo rii pe ọmọ tuntun lo n sunkun ninu ṣalanga yii, ki i ṣe adiẹ rara, nibẹ lo si ti fígbe ta sita, ti wọn fi lọ pe awọn to yọ ọmọ naa jade.
No comments:
Post a Comment