O PARI, WỌN JU KABIYESI ATI PASITỌ S'ATIMỌLE LORI ẸSUN IJINIGBE, BẸẸ NI WỌN TUN PA OṢIṢẸ NDLEA MEJI DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 4, 2020

O PARI, WỌN JU KABIYESI ATI PASITỌ S'ATIMỌLE LORI ẸSUN IJINIGBE, BẸẸ NI WỌN TUN PA OṢIṢẸ NDLEA MEJI DANU

Orin maa lo, a ko fẹ o mọ l'awọn araalu Awara n'ijọba ibilẹ Oguta, ipinlẹ Imo n kọ fun ọba wọn, Eze Andrew okuewgbunuwa, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59) n'igba t'ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lori ẹsun ijinigbe ati ipaniyan.

Ọjọ Ajẹ, Mọnde ana Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, Isaac Akinmoyede f'oju Kabiyesi naa ati Pasiọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Caleb Agu at'awọn mi in han f'awọn oniroyin, to si ni wọn jọ n ṣiṣẹ kan naa ni.

Kabiyesi naa la gbọ pe o jẹ agbodegba, baba isalẹ ati igilẹyin-ọgba f'awọn adigunjale ati ajinigbe, ti wọn si ni Pasuitọ Agu naa lo n lewaju gbogbo iṣẹ buruku wọn.

Akinmoyede nígba to n sọrọ sọ pe awọn eeyan naa ni wọn pa awọn oṣiṣẹ NDLEA meji kan ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin, to si ni Kabiyesi yii lo maa n gbe mọto silẹ fun wọn lati ṣiṣẹ ibi wọn.

Owo ti ko din ni miliọnu mẹrin le diẹ (N4.2m) la gbọ pe awọn ọlọpaa gba lọwọ wọn nigba ti ọwọ palaba wọn segi, bẹẹ ni wọn tun gba ibọn AK-47 mẹrin, ibọn nla kan to jẹ ti oṣiṣẹ NDLEA ti wọn pa at'awọn ọta ibọn ọgọfa pẹlu giipu Lexus SUV kan.

Miliọnu mẹta naira la gbọ pe Kabiyesi naa gba ninu miliọnu meje naira ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn ji gbe.

Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu to kọja lọwọ awọn ọlọpaa kogberegbe, SARS tẹ wọn lagbegbe Umuokuzu, ijọba ibilẹ Ohaji/Egbema, ipinlẹ Imo.

Awọn tọwọ tun tẹ ni Uzoma Bernard, ẹni ọdun marundinlaadọrin (65); Fabian Obioha, ẹni ọgọ ọdun (60); Ogechi Obioha, ẹni ọgbọn ọdun (30); Kennedy Okwuonu, ẹni ogoji ọdun (40); Ebenezer Obioha, ẹni ọdun mejidinlogoji (38); ati Ikechukwu Njoku, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32).

AWIKONKO gbọ pe mọto SUV ti wọn gba lọwọ wọn ni wọn ko ri nọmba idanimọ to wa lara ẹ, iyẹn URM 404 EL ninu akọsilẹ ajọ FRSC.

N'igba to n sọrọ, Kabiyesi naa sọ pe ki i ṣe akọkọ ree toun yoo maa gba owo lọwọ wọn, ati pe oun loun maa n gbe mọto silẹ fun n'igba ti wọn ba fẹ lọ ọ ṣiṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI