Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti rawọ ẹbẹ sita wi pe ẹnikẹni to ba ri ọmọ ọdun mọkandinlogun kan, Sunday Ṣodipẹ t'ọwọ tẹ laipẹ yii lori ẹsun ipaniyan lagbegbe Akinyẹle n ílu Ibadan, ko tete fi to wọn leti.
Komiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Joe Nwachukwu Enwonwu lo fi iroyin naa lede lonii pe Sunday ti poora lahamọ awọn to wa latigba to ti foju ba ile ẹjọ.
Ohun t'awọn to gbọ ọrọ naa n sọ bayii ni pe bi ko ba lọwọ kan ninu, ko ṣee ṣe ki Sunday poora ninu ahamọ ọlọpaa to wa, nigba ti ki i ṣe pe ọlọpaa kan ṣoṣo tabi meji lo wa ni teṣan to ti d'awati, ti wọn l'awọn ọlọpaa to wa nibẹ le ni mẹwaa.
No comments:
Post a Comment