NITORI IWA AFOJUDI, WỌN LE MINISITA FUN ETO ILERA DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 21, 2020

NITORI IWA AFOJUDI, WỌN LE MINISITA FUN ETO ILERA DANU

Aarẹ orilẹ-ede Madagascar, Andry Rajoelina ti le minisita fun ọrọ eto ilera orilẹ-ede naa, Ahmad Ahmad danu lori ẹsun wi pe o n wa iranlọwọ awọn eleto ilera kaakiri agbaye kiri.

Idaduro yii waye lẹyin oṣu kan ti Ahmad gba Aarẹ Rajoelina lamọran wi pe ko jẹ k'awọn wa iranlọwọ awọn orilẹ-ede lọ lori bi ajakalẹ arun koronafairọọsi ṣe n f'ẹmi awọn araalu ṣofo danu, ti arun naa si n tan si i.

Oṣu keje ọdun yii ni arun naa ti wọn tun n pe ni Covid-19 gbọna iyalẹnu yọ si wọn, lẹyin ti wọn ti polongo wi pe oogun ibilẹ l'awọn yoo fi koju ẹ.

Eyi ni wọn loo mu ki minisita naa kọ'we si awọn eeyan lagbaye lori ọrọ ilera lati wa a ran wọn lọwọ, ki wọn si pese awọn irinṣẹ to le ddẹkun arun naa l'awọn ọsibitu wọn.

Idi ree ti Aarẹ Rajoelina fi sọ pe iwa afojudi ni minisita naa wu nitori to ni ko fi ọrọ naa lọ oun tabi awọn alakoso ko to o gbe igbesẹ.

Loju ẹsẹ lo ti kede Jean Louis Hanitrala Rakotovao gẹgẹ bi minisita tuntun fun ọrọ eto ilera

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI