MAN CITY L'AWỌN ṢETAN LATI RA MESSI LỌRỌỌYAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 29, 2020

MAN CITY L'AWỌN ṢETAN LATI RA MESSI LỌRỌỌYAN

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti sọ ọ sita pẹlu igboya wi pe awọn ṣetan lati ra gbajugbaja ọmọ orilẹ-ede Argentina to tun jẹ balogun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi.

Man City sọ pe ko si nnkan t'awọn tun n duro de bi ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ba ṣetan lati ta a fun ẹgbẹ agbabọọlu miran.

Yatọ si pe Man City n wa gbogbo ọna lati Messi, bẹẹ l'awọn mi in naa n wa a, koda ti wọn ni ẹgbẹ agbabọọlu Paris Saint-Germain naa ṣetan lati tọwọ bọwe adehun pẹlu rẹ, lẹyin ti won sọ pe Neymar ba Messi sọrọ foonu l'Ọjọbọ, Tọside ijẹta lori pe yoo ṣeeṣe fun un lati wa si liigi akọkọ, iyẹn League 1.

Igbagbọ pupọ awọn ololufẹ ere idaraya ti bọọlu alafẹsẹgba ni pe Messi yoo b'awọn alaṣẹ Barcelona ṣe ipade lori bo ṣe fẹẹ kuro ninu ikọ naa. 

Man City si ti duro tan bayi pe iye Messi ba loun fẹẹ gba l'awọn yoo fun un lẹyin adehun ti wọn ba ṣe pẹlu ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI