MAKINDE FASUNLE ṢE IKINNI IYALẸNU ỌJỌ-IBI FUN OLOYE ṢHILE ALEXANDRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 27, 2020

MAKINDE FASUNLE ṢE IKINNI IYALẸNU ỌJỌ-IBI FUN OLOYE ṢHILE ALEXANDRA


Wọn ni yinniyinni k’ẹni-o-ṣe mi in lo n mu ki oloore tubọ tẹsiwaju ninu awọn iwa rẹ, bẹẹ si ree, bi a ba ṣeni loore, ọpẹ la n du, eyi lo mu ki gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Oloye Makinde Fasunle t’ọpọ awọn eeyan n pe ni Sẹnetọ Pedepede ṣe ikini iyalẹnu fun gbajumọ ẹlẹyinju aanu nni, Oloye Muraina Waheed Ọlanṣhile t’awọn eeyan tun n pe ni Ṣhile Alexandra.
 

Oloye Muraina Ọlanṣhile ni alaṣẹ ati oludasile ileeṣẹ Shile Alexandra Nigeria Limited kaakiri agbaye, to si ti lo ileeṣẹ naa lati fi ran pupọ awọn eeyan lọwọ jakejado orilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agbaye.

 

Oni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2020 ni ayajọ ayẹyẹ ọjọ ibi gbajumọ ẹlẹyinju aanu, ẹni táwọn eeyan fẹran rẹ gidigidi.

 


Eyi lo mu ki ọkan lara awọn ogbontarigi pedepede n’ipinlẹ Ogun, Oloye Makinde Fasunle ti awọn ololufẹ rẹ tun n pe ni Baba Owuye ṣe ikini ara-ọtọ lati fi ki Oloye Alexandra fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi naa, to si tun n jẹ ko di mimọ pe oun ko le gbagbe rẹ titi lai, ati pe titi ayeraye l’oun yoo maa fi dupẹ lọwọ ẹ f’awọn nnkan to ti ṣe fun un.

 

Ninu ikede oniṣẹju mẹta ati mẹẹdogun (03:15minutes) ni Fasunle ti sọ diẹ lara awọn ipa ti Oloye Alexandra ti ko n’igbesi aye rẹ, to si tun n rawọ ẹbẹ s’awọn eeyan lati ba a dupẹ gidigidi.

 


Fasunle ni “Bi mo ba kọ, ti mo sọ pe mi o ni ki ọlọjọ, a jẹ pe mo fẹẹ ya abara-moore-jẹ ni. O ku oriire o Ọlọlajulọ Oloye Muraina Waheed Ọlanṣile, wa a ṣe akaimọye ọdun laye, tori pe gbogbo ọjọ kejinlọgbọn oṣu kẹjọ ni ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

 

“Ọlọjọ ibi, alaṣẹ Shile Alenxandra Nigeria Limited to kari aye, mo n gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun ẹ pẹlu obitibiti owo ninu apo owo rẹ. Olowo ma ja si koto, ma ja si gegele, eyi ti a ba jẹ ninu owo ẹ ni. Emi Iṣọla jẹ ninu owo Muraina Ọlanṣile, mi o jẹ ba wọn bu ọ tori pe ẹni to ba jẹ ninu owo Jimọ lo n pe e l’ọjọ nla.

 

“Aṣọdunmọdun lo n ṣ’awo aṣọdunmọdun, aṣoṣumoṣu lo n ṣ’awo aṣoṣumoṣu, bo ba wu Olugbọn ko jiire, agunla Olugbọn, bo ba wu Arẹsa ko jiire, agun tẹtẹ Arẹsa, bi Ṣile Alexandra ba ti jiire abuṣebuṣe. Olowo ori ibeji lọọdẹ ọkọ, olowo ori iyale Muraina, iyẹn Taiwo Esther Muraina.

 

“Igba ti ẹyin tiẹ rọ lo jẹ ki ọmọ meji tun w’ọle ọla wẹrẹ. Ṣile Alexandra, olowo ori Ọmọlara, ade ori Rẹmilẹkun kan ti o kọ bi, mo ki ọ ku ewu ọjọ ibi. Iran akala ko ni ṣalai lo ẹgbẹrun ọdun laye, to ba ku ọla, yoo tun ku ọla ni, tori pe bi agbọrin ba ti sin in, ṣe ni ọjọ iku rẹ n yẹ. Ṣile Alexandra ọlọjọ ibi, oo kuku ni ba wọn n’ọja warawara.

 


“Olowo alaanu, af’owo ṣere ma f’owo ṣ’eka, eeyan ko ni ba ẹkun dele Alexandra ki tọhun ma ba ẹrin pada sile. Ọtọ ni ka lowo lọwọ, ọtọ ni ka mọ bi wọn ti n na a, ṣugbọn mejeeji pata ni Ọlọrun Ọba mi oke fun Ṣile Alexandra. O lowo lọwọ, o tun mọ bi wọn ṣe n na a, Ọlọrun tun wa fi oju aanu si i l’ojulati maa fi ṣaanu fun gbogbo eeyan.

 

“Bi mo ba parọ, ẹ beere lọwọ Ọba orin Saheed Oṣupa, Ṣẹfiu Alao, Waisu Alabi Pasuma, to si jẹ pe gbogbo ohun ti mo sọ yii, bẹẹ gẹlẹ lẹ o ba a.”

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI