KỌMIṢANA MI-IN TUN KỌWE F'IṢẸ SILẸ LOJIJI NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 29, 2020

KỌMIṢANA MI-IN TUN KỌWE F'IṢẸ SILẸ LOJIJI NI KWARA

 

Iyalẹnu nla lo n jẹ f'awọn eeyan, paapaa awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara lori b'awọn alabaṣiṣẹpọ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe n kọwe f'iṣẹ silẹ lasiko yii. 

L'ọsẹ to kọja, Ọjọgbọn Suleiman lo kọwe f'iṣẹ silẹ gẹgẹ bi i oludamọnran pataki fun Gomina lori eto ilera ipinlẹ naa, ṣugbọn i bayii, Ọnọrebu Aisha Ahman-Pategi naa lo tun kọwe f'iṣẹ silẹ gẹgẹ bi i kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ (Special Duties) l'ọjọ Ẹti, Fraide ana.
 
Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ni Ọnọrebu (Hajia) Ahman-Pategi, ko to di pe Gomina AbdulRazaq tun igbimọ rẹ to, to si sọ ọ di kọmiṣanna fun akanṣe iṣẹ.

Ninu lẹta to kọ lati f'iṣẹ silẹ lo ti sọ pe inu oun dun lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan oun ninu ijọba ipinlẹ Kwara, paapaa ninu ijọba Gomina AbdulRazaq.
 
Loju ẹsẹ nijọba ti tẹwọ gba lẹta naa, to si gbadura pe yoo tubọ ga ju ipo to fi silẹ lọ pẹlu ogo Ọlọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI