IKUNLẸ ABIYAMỌ O! BAALE ILE ỌGBỌN F'IPA BA ỌMỌ ỌDUN MẸRINDINLOGUN LAṢEPỌ, WỌN FA ABẸ RẸ YA PẸRẸPẸRẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 21, 2020

IKUNLẸ ABIYAMỌ O! BAALE ILE ỌGBỌN F'IPA BA ỌMỌ ỌDUN MẸRINDINLOGUN LAṢEPỌ, WỌN FA ABẸ RẸ YA PẸRẸPẸRẸ

'Ara mee riri, mo ri ologbo latẹ' lorin to n tẹnu pupọ awọn eeyan jade nigba ti wọn gbọ pe awọn baale ile ti ko din ni ọgbọn f'ipa ko ibasun f'ọmọdun mẹrindinlogun.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Eliat l'orilẹ-ede Israel n'iṣẹlẹ agbọyanu naa ti waye.
 
Funra ọmọdebinrin naa ni wọn lo lọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti wi pe awọn eeyan naa rọ oun ni ọti yo bamu ni otẹẹli, ki wọn to o f'ipa ko ibasun f'oun.
 
AWIKONKO gbọ pe pupọ ninu awọn eeyan yii ni wọn ya fọnran bi wọn ṣe n ko ibasun f'ọmọ naa lọwọ sori foonu wọn, ṣugbọn ti ọwọ ti pada tẹ ọkan lara wọn ti wọn l'ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ni.
 
Wọn ni ṣe ni ọmọdebinrin naa tẹle awọn ọrẹ rẹ lọọ gbadun ara wọn ni otẹẹli naa, ibi ti wọn l'ọmọ naa ti lọọ ṣẹyọ ni baluwẹ la gbọ pe wọn ti tẹle e lẹyin, ti wọn si ko ibasun fun un karakara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI