Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe Sẹnetọ to ṣoju ẹkun Ila-Oorun n'ile igbimọ aṣofin agba orilẹ-ede yii laarin ọdun 2015 si ọdun 2019, Ọmọba Buruji Kaṣamu ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta.
Irọlẹ ana to jẹ ọjọ Satide, Abamẹta ana ni iroyin iku Kaṣamu gba igboro kan, to si ba awọn ololufẹ, paapaa awọn alatilẹyin rẹ lọkan jẹ pupọ.
Ọsibitu First Cardiological Services to wa n'ilu Eko, iyẹn nibi ti olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ Buhari tẹlẹri, Abba Kyari ati gomina ana nípinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ku si naa ni Buruji Kaṣamu ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Bi iroyin naa ṣe jade sita l'awọn agba oṣelu ti bẹrẹ si i fi atẹjade ibanikẹdun ranṣẹ, ti wọn si n sọ iru eeyan ti Kaṣamu jẹ si wọn.
Lara awọn to fi lẹta ibankẹdun ranṣẹ ni Gomina Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun; Sẹnetọ Ibikunle Amosun ati Ọtunba Gbenga Daniel ti wọn jẹ gomina ana ati ijẹta n'ipinlẹ Ogun; Ọnọrebu Ọladipupọ Adebutu; Ọnọrebu Sikirulai Ogundele; Ọgbẹni Reuben Abati to fẹẹ ṣe igbakeji Kaṣamu nibi idibo ọdun 2019 at'awọn mi in. Gbogbo wọn ni wọn fi aidunnu ati ibanikẹdun wọn han lori iku ẹ.
Bakan naa ni Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣegun Ọbasanjọ fi lẹta ibanikẹdun rẹ si gomina Dapọ Abiọdun, ṣugbọn lẹta naa da awuyewuye gidi silẹ, paapaa lawujọ awọn oloṣelu at'awọn araalu.
Ninu lẹta ti Ọbasanjọ kọ lo ti darukọ Buruji Kaṣamu gẹgẹ bi Ẹṣhọ Jinadu, to si ni pẹlu bo ṣe sa fun ijiya ẹsun egboogi oloro ti wọn fi kan an lorilẹ-ede Naijiria ati awọn orilẹ-ede mi in to, ko ri ọna abayọ lati bọ lọwọ iku.
Ko pẹ ti lẹta Ọbasanjọ jade sita l'awọn kan ti wọn jẹ alatilẹtin naa ti da Ọbasanjọ lohun pada wi pe ọrọ ti ko yẹ ko jade lẹnu agbalagba bi i tiẹ lo sọ sita yẹn, ti wọn si ni bi inu ba tiẹ n bi Ọbasanjọ si Kaṣamu nígba aye rẹ, ko yẹ ko jẹ pe ṣe lo tun maa fi iku yọ ọ.
Bakan naa ni Gomina ana n'ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe naa ju bọmbu ọrọ lu Ọbasanjọ wi pe ko si nnkan ti Kaṣamu ṣe n'idi oṣelu ti ki i fi i tọ Ọbasanjọ leti, ati pe Ọbasanjọ ko le sọ pe oun ko fun Kaṣamu lamọran nidi oṣelu.
Fayoṣe ni igba ti Kaṣamu wa laye lo yẹ ki Ọbasanjọ sọ iru ọrọ yii, ko si yẹ ko jẹ pe igba to ku tan lo ṣẹṣẹ ma maa sọ isọkusọ lẹnu. Bẹẹ ni Fayoṣe sọ pe asiko iku Ọbasanjọ ti n sunmọ etile, koun naa si duro de igba t'awọn eeyan yoo sọ iru ọrọ abuku bayii, lẹyin to ba ku tan.
Bo ti;ẹ jẹ pe awọn kan fara mọ ọrọ ti Ọbansajọ sọ, ṣugbọn sibẹ, ọna ti wọn lo o gbe ọrọ naa gba ni wọn tun sọ pe o ku diẹ kaato.
No comments:
Post a Comment