ÌJỌBA MI KO LẸBỌ-LẸRU O - GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ PARIWO SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 4, 2020

ÌJỌBA MI KO LẸBỌ-LẸRU O - GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ PARIWO SÍTA


Orin 'ọwọ mi má rèé funfun nẹnẹ' ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman AbdulRazaq kọ, tó sì tún n pariwo sita wi pe ijọba oun ko lẹbọ-lẹru rara, to si ni anfaani ṣi silẹ funfun gbogbo awọn olutọpinpin ni Naijiria ati kaakiri agbaye lati wa a ṣe iwadii bi wọn ṣe n na owo wọn.

Alẹ ọjọ Aje, Mọnde ana ni Gomina Abdulrazaq sọrọ yii lasiko to n gbe igbimọ ẹlẹni mẹjọ kan kalẹ kalẹ lati tọpinpin owo ọọdunrun miliọnu (N300m) naira ti gbogbo awọn ijọba ibilẹ n'ipinlẹ naa gba fun idagbasoke.

Igbimọ naa ti Adajọ-fẹyinti Matthew Ọlabamiji Adewara jẹ alaga rẹ, ni Gomina Abdulrazaq ni ki wọn ṣe iwadii owo t'awọn ijọba ibilẹ naa gba lọwọ ijọba apapọ laaarin ọjọ kọkandinlọgbọ oṣu karun ọdun 2019 si asiko yii.
Lara awọn ti wọn tun wa ninu igbimọ naa l'awọn aṣoju ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ; aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa; Arabinrin Sabitiyu Grillo ti wọn yan gẹgẹ bi akọwe; Arabinrin Titilayọ Adedeji; Alaaji Buba Ibrahim; Agbẹjọro Aisha Bello Mohammed ati Alaaja Asmau Apalando.
 
AWIKONKO gbọ pe laraawọn nnkan ti wọn yoo ṣe iwadii rẹ ni awọn owo ti wọn gba lọwọ ijọba apapọ; awọn owo ti wọn pa wọle; awọn owo to gba ibomiran wọle; ọọdunrun miliọnu naira t'ijọba Kwara gba lọwọ ijọba ibilẹ; at'awọn mi in laaarin ọsu karun ọdun to kọja si asiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI