Bi wọn ba gun ẹṣin ninu ijọba ipinlẹ Kwara lasiko yii, wọn ko nii kọsẹ rara pẹlu iranlọwọ ti wọn ni ajọ agbaye to n ṣe iranlọwọ pajawiri f'awọn ọmọde, iyẹn United Nations International Children Emergency Fund, UNICEF ṣe fun wọn ni gbogbo igba.
Laipẹ yii ni ijọba gbe oṣuba kare fun ajọ naa lori awọn ipa manigbagbe ti wọn n ko n'ipinlẹ naa, eyi ti wọn loo ti le ni ọgbọn ọdun titi di asiko yii.
N'igba to n sọrọ, Kọmiṣanna fun eto iṣuna n'ipinlẹ naa, Arabinrin Florence Ọlasumbọ Oyeyẹmi lasiko to n ṣe abẹwo ṣe lọ sibi idanilẹkọọ kan ti wọn ṣe agbatẹru ẹ pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ eto iṣuna owo naa lo ti sọ pe awọn ko le ṣai dupẹ lọwọ ajọ UNICEF.
Idanilẹkọọ naa ti wọn pe ni Monitoring and Evaluation Policy lo waye laipẹ yii, ohun si lo jẹ pe ipinlẹ Kwara ni ipinlẹ keji lorilẹ-ede Naijiria ti yoo ṣe agbekalẹ rẹ lati fi jẹ k'awọn eeyan mọ pe ko s'ohun t'awọn n gbe pamọ ninu iṣejọba wọn.
No comments:
Post a Comment