Bi iroyin naa ṣe jade sita l'awọn akọroryin ọhun ti bẹrẹ si i fo fáyọ wi pe oriire nla lo wọle tọ awọn wa. Miliọnu mejidinlogun din diẹ (17,760,881) naira la gbọ pe owo ti Gomina AbdulRazaq bu ọwọ fun atunkọ ati atunṣẹ ileeṣẹ awọn akọroyin naa.
Akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ. Ninu atẹjade naa lo ti fi ye wa pe oṣu mẹta pere ni wọn fun awọn agbaṣẹṣe lati fi ṣe atunkọ ati atunṣe naa.
A gbọ pe gbogbo nnkan to ni i ṣe pẹlu igbe-aye irọrun f'awọn akọroyin naa ni wọn fẹẹ fi ta awọn eeyan lọrẹ pẹlu ileri to ṣe fun wọn lasiko to lọ ṣe abẹwo ojiji si wọn lọjọ kọkanlelogun oṣu kinni ọdun yii.
AWIKONKO gbọ pe awọn adari ẹgbẹ oniroyin ni wọn kọ iwe ẹbẹ 'Ẹ gba wa' lọ s'ọdọ gomina lati ran wọn lọwọ lori atunṣe ileeṣẹ wọn to ku diẹ kaato, eyi lo si mu ki gomina ṣeleri fun wọn wi pe ijọba oun yoo wa nnkan ṣe si i laipẹ.
N'igba to n sọrọ alaga awọn akọroyin nípinlẹ naa Malaamu Umar Abdulwahab ati akọwe ẹgbẹ naa, Diakoni Ọmọtayọ Ayanda dupẹ lọwọ gomina fun mimu ileri ṣe, bẹẹ ni wọn ṣeleri ajọṣepọ to peye fun laaarin awọn ati ijọba.
No comments:
Post a Comment