...Gomina ti ko fẹ ilọsiwaju ni
Gomina ana n'ipinlẹ Ondo, Oluṣẹgun Mimiko ti ṣapejuwe Gomina Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi ẹni ti ko nifẹ ilọsiwaju, pẹlu bo ṣe sọ pe o ti pa ẹka eto ilera n'ipinlẹ naa ti.
O ni Gomina ti ko ba ti le ṣe nnkan t'awọn araalu n reti tabi fẹ lati ọwọ ẹ ki i ṣe ẹni to nifẹ ilọsiwaju, ti wọn si gbọdọ gba a danu.
Mimiko lo sọrọ yii lasiko to n gba igbakeji Gomina Akeredolu, Ọgbẹni Agboọla Ajayi to tun ti lọ sinu ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party lati jade dupo gomina ipinlẹ naa lalejo ninu ile ẹ to wa n'ilu Ondo.
Nibẹ ni Mimiko ti ṣalaye pe aimọye ọrọ lo n gbe inu oun lati sọ nipa ijọba Akeredolu, eyi to ni ko bojumu, paapaa lẹka eto ilera, to si ni asiko ọrọ ko ti i to.
O ni latigba ti Akeredolu ti wa n'ipo naa, ko ti i ṣe idaji awọn iṣẹ akanṣe toun ṣe laarin ọdun mẹrin ijọba oun. Nibẹ lo si ti ni o ti di dandan k'awọn araalu dan ijọba mi in wo, ati pe ki wọn gbaruku ti Ajayi nibi idibo to n bọ lọna lọjọ kẹwaaa oṣu kẹwaa ọdun yii.
No comments:
Post a Comment