FỌLÁKẸ́ ADURAGBEMI, OṢOGBO - Ìtàn tuntun ni Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí ìpínlẹ̀ Kwara tún fi balẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì, Fraide àná nígbà tí àwọn igbimọ alakoso, ìyẹn State Executive Council n'ipinlẹ náà bù ọwọ lu idasilẹ eto ikansira-ẹni tigbalode, Information Communication Technology àti Ilorin Visual Arts.
Lára àwọn ìpinnu àti ètò agbekalẹ Gómìnà AbdulRazaq láti mú ìdàgbàsókè bá eto ọ̀rọ̀ ajé n'ipinlẹ Kwara ló wà sì ìmúṣẹ yìí.
Níbi ìpàdé igbimọ amuṣẹṣe náà tó wáyé lórí ayélujára làwọn ọmọ igbimọ náà tí jíròrò lórí eto yìí, kò tó di pé wọn fi ontẹ luu. Yàtọ̀ sí èyí, wọn tú bù ọwọ lu dídá ọda sì òpópónà Iléṣà Baruba Gwanara.
Ọọdurun miliọnu dín diẹ {N265,412,446.50} ni owó náà tí wọn bù ọwọ lu fún ileeṣẹ Messrs Duravil Engineering Ltd láti fi parí òpópónà náà.
Kọmiṣanna fún eto àkànṣe iṣẹ́, Suleiman Rotimi Iliasu sọ fún igbimọ náà pé oṣù kẹwàá ọdún 2013 ni wọn ti kọkọ gbé iṣẹ́ ibi náà fún ileeṣẹ yìí ni biliọnu aabọ náírà {1,560,102,954.58} tẹ́lẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé biliọnu méjì lè diẹ N2,156,953,404.58 àti N2,361,904,549.95 ni wọn gbé owó náà sì lọdun 2015 ati 2017. Bó ṣe kú díẹ̀ kí sáà ìṣàkóso náà parí ni wó tí tún ṣe agbeyẹwo ẹ, tí wọn sì fẹnuko sì biliọnu mẹta dín díẹ̀ náírà, N2,782,716,900.95.
Iliasu ni gbèsè tó wà nílẹ̀ láti fún ileeṣẹ náà jẹ N934,587,553.50, ṣùgbọ́n lẹ́yìn asọyepọ tó kún ojú òṣùwọ̀n làwọn fẹnuko láti san {N265,412,446.50} pẹ̀lú ìlérí wí pé alopẹ ni òpópónà náà yóò jẹ, èyí tó mú kí gbèsè tí wọn yóò san jẹ́ N1,200,000,000.00.
No comments:
Post a Comment