Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí ìpínlẹ̀ Kwara tí bá igbakeji rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi yọ lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tó ń ṣe lónìí, ọjọ́ Kínní oṣù kẹjọ ọdún 2020.
Ninu ọ̀rọ̀ ikinni náà tó fi ranṣẹ sì Alabi lọsan òní, tó sì tún gbé e sórí ìkànnì ayélujára Twitter ni Gómìnà AbdulRazaq ni ṣàpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bí èèyàn jẹjẹ pẹ̀lú ọkàn akíkanjú tó sì ń ṣiṣẹ́ takuntakun.
Ó ní Alabi jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó sì ń fẹ́ ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú àṣeyọrí ìjọba wọn.
Bẹ́ẹ̀ lo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run túbọ̀ máa bukun ẹ láti lè jọ gbé ìpínlẹ̀ náà lárugẹ.
No comments:
Post a Comment