GBAJUMỌ ỌJA TUN JONA, L'AWỌN ARAALU BA DANA IYA F'AWỌN PANAPANA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 16, 2020

GBAJUMỌ ỌJA TUN JONA, L'AWỌN ARAALU BA DANA IYA F'AWỌN PANAPANA

'Nibo la fẹẹ gba, gbese nla re o' lariwo ibanujẹ to n tẹnu awọn ara gbajumọ ọja Igbudu, to wa nilu Warri, ipinlẹ Delta lonii ọjọ Aiku, Sannde lori bi ina ṣe ṣẹyọ lapa kan ọja naa, to si jo ọpọlọpọ ṣọọbu nibẹ.
 
Ọsan onii la gbọ pe ina naa deede ṣẹyọ lai ro tẹlẹ ninu ọja yii, to si jo awọn ọja olowo iyebiye to le ni miliọnu naira di eeru.
 
Titi di asiko ta a kọ iroyin yii tan la ko ti i le sọ pato nnkan to ṣokunfa ijamba ina naa, eyi ti a gbọ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ni wọn pa ina naa.
 
Eyi to n jẹ iyalẹnu ni b'awọn eeyan ṣe bẹrẹ si i sọ okuta nla-nla f'awọn oṣiṣẹ panapana yii lori ẹsun wi pe wọn pẹ ki wọn to o debẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI