Iroyin ayọ̀ kan tó tẹ AWIKONKO àti gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ báyìí ni pé ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Arábìnrin Fọlákẹ́ AbdulRazaq tí ṣe ìlérí wí pé òun yóò dá sí ọ̀rọ̀ iyale ilé kan tí ọkọ rẹ lè òun àti ọmọ rẹ dànù lórí ẹyinju tí wọn ní.
Laipẹ yìí ni akọroyin kan ṣe ifọrọwerọ pẹ̀lú obìnrin náà, Risikat pẹ̀lú ọmọ rẹ tó jẹ́ obìnrin, níbi tó ti ṣàlàyé nnkan ti ojú rẹ rí nílé ọkọ, èyí tó mú kí ọkọ rẹ sá foun àti ọmọ rẹ.
Ifọrọwerọ náà káàkiri débi wí pé ó ṣe àwọn èèyàn láàánú, lára àwọn tó sì ṣe láàánú ni Arábìnrin Fọlakẹ AbdulRazaq tó jẹ́ ìyàwó Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì ayélujára tí Twitter laipẹ yìí, obìnrin àkọ́kọ́ nipinlẹ náà sọ pé òun ti ṣetan nípasẹ̀ àjọ aláàánú òun láti fi dá sí ọ̀rọ̀ obìnrin náà àti ọmọ rẹ, tó sì tún ní o ṣeé ṣe koun yanjú ìṣòro tó wà láàárín òun àti ọkọ rẹ.
No comments:
Post a Comment