FANI KAYỌDE KABUKU NLA NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 25, 2020

FANI KAYỌDE KABUKU NLA NITA GBANGBA


Titi di asiko ti a kọ iroyin yii tan l'awọn ọmọ Naijiria, at'awọn eeyan kaakiri agbaye ṣi n bu ẹnu atẹ lu minisita tẹlẹri f'ọrọ ọkọ ofurufuru (Aviation) lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Fẹmi Fani-Kayọde si ọkan lara awọn akọroyin ileeṣẹ Daily Trust.

Ibeere ti wọn ni akọroyin naa, Eyo Charles beere lọwọ Fani Kayọde nipa awọn irin-ajo rẹ ni wọn loo bi i ninu, to fi bẹrẹ si i sọrọ buruku si akọroyin naa.

Fọnran ifọrọwerọ naa lo gba ori ẹrọ ayelujara kan, t'awọn eeyan si n sọrọ buruku si i pe ko yẹ ko bu akọroyin naa, nitori pe iṣẹ rẹ lo n ṣe.

Charles ni oun ko kabamọ nipa ibeere toun beere, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo t'oun kabamọ ni pe oun tọrọ aforiji lọwọ Fani Kayọde lori ọna t'oun gbe ibeere naa gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI