Gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara ni wọn la ẹnu wọn, ti wọn ko si le pa a de nígba ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ lorilẹ-ede yii, EFCC kede sita pe awọn ti ṣawari owo ti ko din ni aadoje miliọnu (130m) naira ninu owo t'awọn kan ti ko jẹ ninu ijọba to kọja.
Ọjọru, Wẹside to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq gbe oṣuba kare fun ajọ naa lori bi wọn ṣe n fi inu kan ba wọn lo nipa fifọ ilu mọ kuro lọwọ awọn jẹgudujẹra lawujọ.
Asiko ti adari tuntun fun ajọ naa n'ipinlẹ Kwara, Oseni Kazeem ṣabẹwo si Gomina AbdulRazaq n'ilu Ilọrin lo tu aṣiri yii sita fun Gomina wi pe awọn ti ṣawari aadoje miliọnu naira ninu owo t'awọn kan ko jẹ, to si ṣeleri pe gbogbo owo naa l'awọn yoo ko fun ijọba lẹyin iwadii.
Gomina AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ sọ pe awọn owo naa ti wulo pupọ lati jẹ ki ijọba duro digbi lati oṣu karun ọdun 2019 t'oun ti gba ijọba.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe n'iwọn igba toun ko ti ni nnkan toun fẹẹ gbe pamọ fẹnikẹni, oun nilo lati jẹ k'awọn araalu mọ b'ijọba ṣe n na owo loore-koore.
No comments:
Post a Comment