ẸMIR KANO, ADO BAYERO ṢABẸWO SILU ILỌRIN FUN IGBA AKỌKỌ LẸYIN TO GBA IPO, O TUN BA GOMINA ABDULRAZAQ ṢE IPADE ALAAFIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, August 29, 2020

ẸMIR KANO, ADO BAYERO ṢABẸWO SILU ILỌRIN FUN IGBA AKỌKỌ LẸYIN TO GBA IPO, O TUN BA GOMINA ABDULRAZAQ ṢE IPADE ALAAFIA


'Emi la o ni yọ sí, bá a ti fe o ri, bẹẹ náà ló rí, emi la o ni yọ sí' l'orin tàwọn ọmọ ipinlẹ Kwara, pàápàá àwọn olùgbé ilu Ilọrin nko nigba ti Ẹmir tilu Kano, Alaaji Aminu Ado  Bayero ṣabẹwo s'ilu Ilọrin.

Ohun ti pupọ awọn eeyan ko mọ ni pe ilu Ilọrin ti mama to bi Ẹmir Kano, Ado Bayero ti wa, ti baba rẹ si jẹ ọmọ ipinlẹ Kano.
 
Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe akọkọ ree ti Ado bayero yoo maa ṣabẹwo silu Ilọrin, ṣugbọn akọkọ ree latigba to ti wa nipo Ẹmir.
 
N'igba to n sọrọ, Ẹmir Kano ni adura loun wa a gba nílu Ilọrin gẹgẹ b'oun ṣe maa n wa gba a, ati pe oun tun fi anfaani naa ba Gomina Abudlrazaq kẹdun iku baba rẹ, Alaaji AGF Abdulrazaq, to si n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni "Eredi abẹwo mi ni lati pada wa sile, nibi ti mo ti wa. Ni temi, ko si iyatọ laarin ilu Kano ati Ilọrin. Ile mi ree, ibẹ ni mama mi ti wa, inu mi si maa n dun ti mo ba ti wa sile. Ki i ṣe akọkọ ree ti mo maa n wa, ki i ṣe ẹlẹẹkeji, mi o si le ka iye igba ti mo ti wa sile. Ṣugbọn abẹwo mi yii yatọ s'awọn eyi ti mo ti n wa tẹlẹ nitori pe akọkọ ree ti mo maa wa latigba ti mo ti de ori ipo Emir. Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun eyi.
 
AbdulRazaq ni nu ọrọ tirẹ sọ pe ipo t'awọn ọba wa ninu eto oṣelu lorilẹ-ede Naijiria ko ṣee fọwọ rọti sẹyin, t'awọn oloṣelu si gbọdọ maa bọwọ fun wọn.
 
"Gẹgẹ bi ijọba, a ni ibọwọ nla f'awọn to wa nipo ọba ati oye. Ati pe gẹgẹ bi mo ṣe mọ, pẹlu bo ṣe jẹ pe ipo mẹta nijọba wa, mo gbagbọ pe ipo kẹrin lawọn ọba  wa ninu iṣejọba, idi ree t'awọn ijọba ologun ṣe gbawọn laaye lati da si ọrọ ijọba ibilẹ. 
 
Lara awọn to kọwọrin pẹlu Emir lawọn igbimọa fọbajẹ nilu Kano, at'awọn agbaagba laafin Ẹmir tilu Ilọrin bi i Balogun Gambari, Alhaji Aliyu Adebayo ati Dan Masanin Ilorin, Onimọ-ẹrọ Suleiman Yahya Alapansapa, at'awọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI