ẸGBẸ́ AKẸKỌỌ NI NAIJIRIA, NANS GBE OṢUBA KARE FUN ẸGBẸ́ FIJILANTE N'IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 19, 2020

ẸGBẸ́ AKẸKỌỌ NI NAIJIRIA, NANS GBE OṢUBA KARE FUN ẸGBẸ́ FIJILANTE N'IPINLẸ OGUN


Inu didun ni wọn sọ pe o maa n mu koriya wa, bẹẹ gẹlẹ lori pẹlu bi ẹgbẹ awọn akẹkọọloril-ede Naijria, ẹka ti Zone D ṣe ṣabẹwo iwuri sileeṣẹ ẹgbẹ eleto aabo FIjilante n'ipinlẹ Ogun, eyi ti Kọmanda Nureni Ọlanrewaju Adedoyin jẹ adari rẹ.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana ni abẹwo airotẹlẹ naa waye ni ọfiisi awọn Fijilante to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti ṣe sadankata fun ọga agba naa, Kọmanda Ọlanrewaju Adedoyin lori awọn iṣẹ takuntakun to n ṣe lẹka eto aabo, eyi to f'ọkan awọn araalu balẹ n'irọrun.
 
Nibi abẹwo naa l'awọn oloye ẹgbẹ akẹkọọ yii, Nigerian Students in Southwest Geopolitical Zone (NANS Zone D) ti lo anfaani rẹ lati sọ awọn ipenija to ṣee ṣe ko waye l'awọn ile-ẹkọ giga kaakiri pẹlu bi eto-ẹkọ ṣe fẹẹ bẹrẹ ni pẹrẹu laipẹ.
 
Igbakeji adari ẹgbẹ aa, Kọmureedi Ọladimeji Uthman nibi abẹwo naa tun jẹ ko di mimọ fun ileeṣẹ Fijilante nipa igbogunti iwa ifipanilopọ lawujọ t'awọn n polongo, eyi to sọ pe iwa ibajẹ gba a ni, ko si yẹ lawujọ.
 
Igbakeji KọmandaFijilante, Odogun Olubanjọ to gba awọn akẹkọọ naa lalejo lasiko ti ọga rẹ ko si nile dupẹ gidigidi lọwọ awọn oloye ẹgbẹ naa fi bi wọn ṣe ka wọn kun, ati imọriri iṣẹ wọn lawujọ lati ri i pe iwa ibajẹ d'ohun igbagbe patapata.


Ẹgbẹ awọn akẹkọọ yii wa a sọ pataki abẹwo naa wi pe awọn fẹẹ ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu Fijilante ki ipinu wọn lori ipolongo lati dẹkun iwa ifipanilopọ lawujọ le dinku.
 
Kọmureedi Ọladimeji Uthman to lewaju awọn oloye naa sọ pe awọn kko le ṣai gbe oriyin fun ileeṣẹ Fijilante lori iṣẹ takuntakun wọn, to si tun gba wọn lamọnran lati ṣe ju bi wọn ṣe n ṣe lọ.


Nibẹ ni igbakeji ọga Fijilante n'ipinlẹ Ogun, Odogun Olubanjọ to gba wọn lalejo tun ti gbe fi imọriri rẹ han si Gomina Dapọ Abiọdun pẹlu iranlọwọ rẹ lati gbaruku ti ọrọ eto aabo n'ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI