"Ẹ wa ṣe iribọmi yin pẹlu ọti ti ẹ fẹran ju ninu isin wa ni gbogbo ọjọ Aiku laago mọkanla".
Afojusun ijọ Gabola ni lati gba awọn ọmuti mọra ti awọn ijọ mii kii fẹ ni nkan ṣe pọ pẹlu wọn.
Wọn n ṣe eyi lati fun wọn anfani lati le maa mu ọti lile bi o ba ṣe wu wọn.
Orilẹede South Africa ni ijọ yii wa. Bi o tilẹ jẹ wipe ofin ko faaye gba tita tabi mimu ọti bayii ni orilẹede naa, ijọ ọlọtii Gabola ni eyi n pa awọn lara gidi gan lasiko Covid-19 yii.
"Lonii, ẹnu gbẹ ni Ṣọọṣi wa tori a o fẹ́ lodi si ofin to ba Coronavirus wa".
Olori ijọ Gabola ni "a o ko da ẹṣẹ kankan ni ijọ Gabola, a si korira lilodi si ofin ijọba".
Latorii awọn Biṣọọbu ati gbogbo ijọ lo n gbe nkan lura ki wọn to lọ si Ṣọọṣi naa ti wọn si gbagbọ pe yoo mu ẹmi mimọ sọkalẹ si aarin wọn.
Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ, "Noun Phrase"
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment