Ẹ FARA BALẸ, MI O GBA IṢẸ LỌWỌ AJỌ NCDC O - IBORI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 4, 2020

Ẹ FARA BALẸ, MI O GBA IṢẸ LỌWỌ AJỌ NCDC O - IBORI PARIWO SITA

Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Delta, da sọ pe oun ko tẹwọ gba iṣẹ kankan lọwọ ileeṣẹ to n sọrọ idagbasoke Niger Delta, iyẹn Niger Delta Development Commission, NCDC, eyi ti Minisita Godswill Akpabio fi ẹsun rẹ kan.

Laipẹ yii ni Akpabio darukọ James Ibori mọ awọn orukọ awọn to gba iṣẹ akanṣe lọwọ ileeṣẹ NCDC, eyi to n da wahala silẹ bayii.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Ibori, Ọgbẹni Tony Eluemunor fi sita lo ti ni k'awọn eeyan farabalẹ lati gbọ alaye t'oun nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.

"N'igba ti mo gbọ nipa ẹsun wọn fi kan ọga mi wi pe o gba iṣẹ lọwọ ileeṣẹ NCDC laarọ yii, eyi ti Gomina ana nípinlẹ Akwa-Ibom, Sẹnetọ Godswill Akpabio sọ, to si jade lori iwe iroyin. Ọga mi ko ṣetan lati maa jo laaarin ọja gẹgẹ bo ṣe n lọ ninu ọrọ NCDC.

"Ibori ti ṣetan lati jẹ ko ye awọn eeyan, nitori pe awọn ololufẹ, ọrẹ ati ojulumọ ti n pe e latigba tiroyin naa ti jade. O fẹẹ fi asiko yii sọ pe ko bẹbẹ fun iṣẹ, tabi gba iṣẹ tabi ṣiṣẹ kankan fun ileeṣẹ NCDC tabi awọn ileeṣẹ ijọba kankan."

O ni lasiko ti Ibori fi wa n'ijọba, ko sẹni to fẹsun kan an wi pe o gba iṣẹ funra rẹ, depodepo wi pe yoo kuna ninu ijọba rẹ. Bẹẹ lo ni ki Akpabio farabalẹ lati gbajumọ iṣẹ ti wọn gbe lee lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI