Ẹgbẹ agbabọọlu Bayer Leverkusen ti sọ pe awọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni gbedeke ọjọ lati t'ọwọ bọ'we adehun pẹlu gbajugbaja agbabọọlu nni, Kai Havertz.
Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun yii ni Bayer l'oun fun Chelsea da lati t'ọwọ bọ'we adehun naa fun Havertz, ko le darapọ mọ wọn.
Havertz la gbọ pe o ti n wu lati darapọ mọ ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, ṣugbọn ti adehun owo pẹlu Bayer ko ti i wọ laarin wọn.
Aadọrun miliọnu dọla {£90million} la gbọ pe Bayer n beere lọwọ Chelsea lati ta Havertz fun wọn, ṣugbọn aadọrin {£70million} miliọnu ni Chelsea n bẹbẹ fun lati san.
Awọn agbabọọlu Leverkusen’ ni wọn yoo gbaradi lati bẹrẹ ipalẹmọ idije, iyẹn pre-season l'ọjọ Fraide to n bọ lọhun, wọn si ti fẹ mọ nnkan ti yoo ṣẹlẹ lori Havertz ṣaaju ọjọ naa.
No comments:
Post a Comment