AWỌN TO TI LUGBADI ARUN KORONAFAIRỌỌSI TI WỌ ẸGBẸRUN MẸRINLELOGOJI (44,000) BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 4, 2020

AWỌN TO TI LUGBADI ARUN KORONAFAIRỌỌSI TI WỌ ẸGBẸRUN MẸRINLELOGOJI (44,000) BAYII

Alẹ ọjọ Aje Mọnde ana ni ajọ to n ṣabojuto ajakalẹ arun lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Nigeria Centre for Disease Control (NCDC) kede sita wi pe awọn ti ko din ni ọọdunrin-din ni mejila (288) ni wọn tun ti lugbadi arun naa bayii.

Ajọ naa sọ pe eyi ti jẹ ki awọn to tu lugbadi arun naa le ni ẹgbẹrun mẹrinlelogoji 44,129 ni Naijiria bayii.

Ninu ọrọ ti wọn gbe sori ikanni ayelujara agbẹyẹfo (Twitter) ni alẹ naa ni wọn ti ṣalaye bi gbogbo awọn ipinlẹ naa ṣe ni arun Covid-19.


Lagos-88
Kwara-33
Osun-27
FCT-25
Enugu-25
Abia-20
Kaduna-17
Plateau-13
Rivers-13
Delta-10
Gombe-8
Ogun-4
Oyo-3
Katsina-1
Bauchi-1

44,129 - Akojọpọ awọn to ni arun naa
20,663 - Awọn ti ara wọn ti ya
896 - Awọn ti wọn ti ku

Nibẹ ni wọn tun ti jẹ ko di mimọ pe ipinlẹ Eko ni wọn ṣi n lewaju ni nu awọn ipinlẹ to ni arun naa pẹlu 15,355, n'igba ti Abuja, Ọyọ ati Ẹdo ni 3,997, 2,771 ati 2,311.

Bakan naa ni wọn sọ pe ipinlẹ Kogi nikan lo ni eyi to kere julọ pẹlu akọsilẹ marun-un, to si ni ko sẹnikẹni nile ti wọn ti n tọju awọn to ni arun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI