Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba pátápátá káàkiri ìpínlẹ̀ Kwara ni wọn ti ń fò fún ayọ̀ àìlópin báyìí lórí bí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ṣe pàṣẹ pé kí ìdánwò fún igbega lẹ́nu iṣẹ bẹ̀rẹ̀.
Igbega s'awọn ipò l'ẹka eto iṣejọba fún tọdun 2019 ni Gomina AbdulRazaq sọ pé yóò bẹ̀rẹ̀
Ẹ̀ka ileeṣẹ ìjọba tó ń rí sọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́, ìyẹn Civil Service Commission ni Gomina AbdulRazaq pàṣẹ pé kí wọn ṣagbatẹru ìdánwò náà.
Gómìnà fìdí ẹ múlẹ̀ pé eto igbanisiṣẹ náà gbọ́dọ̀ lọ nibamu pẹ̀lú didẹkun itankalẹ àrùn Covid-19.
Àwọn tó wà nipele keje si ipele kẹrindinlogun ni wọn yóò jẹ àǹfààní ìdánwò náà, àti pé àwọn òṣìṣẹ́ tí kò dín ni 1,716 ni wọ́n yóò gbà igbega lẹ́yìn idanwo yìí.
No comments:
Post a Comment