AṢIRI TUNTUN TU LORI GBESE TI GOMINA ABDULRAZAQ BA N'ILẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 25, 2020

AṢIRI TUNTUN TU LORI GBESE TI GOMINA ABDULRAZAQ BA N'ILẸ


Bi iwadii igbimọ ti Gomina AdulRahman AbdulRazaq gbe kalẹ lati ṣe iwadii lori owo ọọdunrun miliọnu naira ti wọn níjọba n yọ lori owo ijọba ibilẹ ṣe n tẹsiwaju, awọn iwadii tuntun tun ti jẹyọ.
 
Lara awọn iwadii naa ni pe lati ọdun 2009 n'ijọba ipinlẹ naa ti n jẹ awọn ijọba ibilẹ lowo to tọ si wọn, bi i ajẹẹlẹ, owo ifẹyinti at'awọn mi in, eyi ti apapọ owo naa jẹ biliọnu mọkanlelogun naira.
 
Akọwe ileeṣẹ to n ri sọrọ owo oṣiṣẹ-fẹyinti l'awọn ijọba ibilẹ, iyẹn Executive Secretary Kwara State Local Government Staff Pension Board, Smaila Oyelowo lo tu aṣiri naa sita laipẹ yii.
 
Smaila lo tu aṣiri naa n'iwaju igbimọ naa ti Adajọ-fẹyinti, Mathew Adewara jẹ alaga rẹ, to si ni gbese ti ijọba AbdulRazaq ba nilẹ jẹ N21,516,812,33.
 
Ọkunrin naa sọ pe miliọnu lọna ọgbọn naira l'awọn n gba tẹlẹ ki Gomina AbdulRazaq to o de l'ọdun 2019, to si ni awọn ti n gba ọgọrun miliọnu naira bayii lati san awọn gbese naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI