AṢIRI ỌKAN LARA AWỌN OṢIṢẸ ỌṢINBAJO TẸLẸ TU S'ỌWỌ IGBIMỌ IWADII AYỌ SALAMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, August 21, 2020

AṢIRI ỌKAN LARA AWỌN OṢIṢẸ ỌṢINBAJO TẸLẸ TU S'ỌWỌ IGBIMỌ IWADII AYỌ SALAMI

Pẹlu aṣiri tuntun to ṣẹṣẹ tu sita s'ọwọ igbimọ to n ṣe iwadii lori ẹsun owo kikojẹ ti wọn fi kan alaga fidihẹ fun ajọ EFCC tẹlẹ, iyẹn Ibrahim Magu, eyi ti Onidajọ Ayọ Salami n dari ẹ lọwọ, afaimọ ni ki amugbalẹgbẹ pataki fun igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Ọṣinbajo tẹlẹri, Donald Wokoma ma na papa bora bayii, tabi ko fi ẹwọn jura lẹyin ti iwadii ba pari.
 
Nibi iwadii igbimọ naa ni aṣiri ti tu pe Donald Wokoma ti fi orukọ ileeṣẹ ẹ gba kọntiraati ti owo ẹ jẹ N250,000,000 naira lọdun 2018, ti wọn ko si ṣiṣẹ naa titi di asiko yii.
 
Wọn ni asiko ti Wokoma jẹ amugbalẹgbẹ lori ọrọ to nii ṣe pẹlu eto iṣuna, iyẹn National Economic Council (NEC). lo ti gba iṣẹ naa, ti ko si ṣe nnkankan lori owo to gba.
 
Ko si nnkan meji to jẹ ki aṣiri naa tu sita bayii ni pe Wokoma nikan lo ni ontẹ (signatory) ile ifowopamọ ileeṣẹ naa lọwọ. Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC to wa a jẹrii lo tu aṣiri yii sita l'Ọjọbọ, Tọside ana fun igbimọ iwadii ti Aarẹ gbe kalẹ.
 
Oṣiṣẹ naa jẹ ko di mimọ pe ọpọ akanṣe iṣẹ ni wọn gbe fun ileeṣẹ ti Wokoma jẹ oludasilẹ rẹ, to si gba owo labẹ eto ti wọn pe ni Presidential Amnesty Programme (PAP).
 
Orukọ ileeṣẹ naa ni wọn pe ni Damijay Integrated Services.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI