Ọjọ mẹta-mẹta n'ijọba faaye rẹ silẹ tẹlẹ wi pe k'awọn eeyan maa fi lọ si ọja pẹlu iboju-bomu, ni ibamu pẹlu ofin to de ipejọpọ elero rẹpẹtẹ lati dẹkun itankalẹ arun Covid-19.
Oni to jẹ ọgbọn ọjọ, oṣu keje ni ilana naa yoo bẹrẹ, nígba ti anfaani yoo ṣi silẹ f'awọn eeyan lati jade lọ ra nnkan ti wọn ba fẹ n'igba to ba wu wọn.
Minisita to n ṣakoso FCT, Malam Muhammad Bello lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Anthony Ogunlẹyẹ n'ilu Abuja.
Beloo ni gbogboọja ni aaye wa fun lati ṣi silẹ fun tita-rira lojoojumọ laaarin aago meje aarọ si aago mẹfa irọlẹ.
No comments:
Post a Comment