WỌN KO TI I RI NỌỌSI TO D'AWATI L'EKOO O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 4, 2020

WỌN KO TI I RI NỌỌSI TO D'AWATI L'EKOO O


Lati ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹfa to kọja la gbọ pe wọn ti n wa ọdọmọbinrin ti ẹ n wo yii. Ẹni ti wọn sọ pe latigba to ti jade nile lọ sibiṣẹ rẹ ni ko ti pada sile.

Wọn ni ko de ibiṣẹ lọjọ naa, bẹẹ si ni wọn ko ti i ri titi ta a fi kọ iroyin yii tan.

Ọsibitu Federal Medical Centre to wa ni Ebute Metta, l'Ekoo la gbọ pe Adetọla ti n ṣiṣẹ nọọsi, ko to o di awati.

 
Wọn wa n bẹ ẹni to ba kofiri ẹ lati fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, tabi ki wọn fi to awọn alaṣẹ ọsibitu FMC, Ebute Metta leti.

Ẹ ṣeun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI