Gbajugbaja Wolii ṣọọṣi Sẹlẹ nni, Wolii Israel Ọladele
Ogundipẹ lo ti di aṣoju ọdọ ilẹ Yoruba {Ọdọ Oodua} bayii, n’igba ti awọn igbimọ iṣakoso
ẹgbẹ yan an.
Ọjọ Aiku Sande ijẹta to kọja yii la gbọ pe wọn gbe
ipo naa fun Wolii Ogundipẹ, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Genesis, t’oun naa si
fi tọkan-tọkan gba a.
Aarẹ ẹgbẹ ọdọ ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Youths
Worldwide, Arẹmọ Ọladọtun Hassan lo kọwọ rin pẹlu igbimọ ẹgbẹ naa, nibi ti wọn ti lọ fi oye naa da Wolii Gẹnẹsis lọla.
Nibẹ naa ni wọn ti fi eto kan lọlẹ, eyi ti wọn pe ni "Iriri Mi Lasiko Ajakalẹ Arun Ọdun 2020: Akanṣẹ Eto Ṣiṣẹ Iṣẹ Agbẹ, "My Pandemic Experience 2020: Agro-Business Scheme Prject", ninu eyi ti wọn fẹẹ fi ran awọn araalu lọwọ n'ipa iṣẹ agbẹ.
N'igba to n sọrọ, Aarẹ ẹgbẹ naa, Arẹmọ Ọladọtun Hassan sọ pe "Oni ti a wa yii gangan kọ ni ifilọlẹ eto yii lẹkunrẹrẹ, ifaara lasan la fẹẹ fi oni ṣe, nitori pe ọna lati fi ran awọn eeyan lọwọ lọna iṣẹ agbẹ.
"Bi konilegbele ṣe n tẹsiwaju, ti ajakalẹ arun naa si n gbilẹ si i, ko si iye ẹgbẹrun marun-un-marun-un ti ijọba apapọ fẹẹ f'awọn eeyan lasiko yii, to fẹẹ dẹkun ebi ọlọjọ pipẹ. Ti a ba walẹ jin, ti a si ronu papọ, apẹẹrẹ rere la maa fi silẹ fun awọn iran to n bọ.
"Eyi ni ẹgbẹ Igbimọ Ọdọ Ilẹ Yoruba kaakiri agbaye mu lokukundun, nitori pe orisun awa ọmọluabi niyẹn, iyẹn iṣẹ agbẹ."
Bakan naa n'igba to n sọrọ lori bi wọn ṣe yan Wolii Gẹnẹsis gẹgẹ bi aṣoju Ọdọ O'odua, Aarẹ Hassan sọ pe "Wolii Ọladele ki i ṣe Kristẹni, bi ko ṣe eeyan Ọlọrun nitori Ọlọrun ko ni ẹsin. A gbagbọ pe bi Kristẹni, Musulumi ba n tẹle yin kaakiri, Jesu Kristi funra rẹ ni awọn ọmọlẹyin, n'igba to de Antioku lo sọ f'awọn ọmọẹyin ẹ pe Kristẹni ni wọn.
"Iran kan ni Gẹnẹsis n dari rẹ bayii, a si n'igbagbọ pe Ọlọrun n mu wa lọ sibi to dara. Ẹni to ṣee f'ọkan tan gidi ni Wolii Gẹnẹsis, idi ree ti a ṣe fi ṣe aṣoju wa. Ayanfẹ Olodumare ni Wolii Gẹnẹsis, ẹni ti Ọlọrun ran ni iṣẹ iyanu.
"Wolii Ogundipẹ ko si fun anfaani ijọ Sẹlẹ nikan, bi ko ṣe fun gbogbo ẹda eeyan lai ni ẹlẹyamẹya ninu. Amulo ni gbogbo ọrọ Wolii Gẹnẹsis. Idi ti a fi ronu lati wa sọdọ yin niyi.
"Eto yii ki i ṣe eto lasan, nitori pe bi a ba bẹrẹ pẹrẹu, ijọba apapọ funra wọn yoo da si i, awọn Gomina naa yoo da si. A fẹ k'awọn eeyan n'ireti bi nnkan to wa nita ba kasẹ nilẹ, wọn ri nnkan gidi tọka si."
Ninu ọrọ rẹ, Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ sọ pe kii ṣe agbara oun, bi ko ṣe pe oore-ọfẹ Ọlọrun.
"Mo fẹran ede ati aṣa Yoruba gidi, ṣugbọn eyi to ba ti ni i ṣe pẹlu bibọ oriṣa, tabi ka tẹriba fun eṣu nikan ni mi o le ba wọn lọwọ si, tori pe ko ba ilana Ọlọrun ti mo n sin mu. Mo maa n sọ f'awọn eeyan pe bi wọn ba ṣoogun owo, wọn ti mu ori ọlọla wa saye ni.
"Awọn eeyan ro pe mo ti de ipele nla, mo fẹ sọ fun un yin pe mo ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, nitori pe mi o ti i bẹrẹ si i jeere iṣẹ ọwọ mi, igba diẹ lo ku. Inu mi dun lati jẹ ọmọ Yoruba. Inu mi si dun pe nigba ti a kọkọ pade, nnkan to wa lọkan mi lẹ n sọ, eyi lo jẹ ki n gba yin.
"Ajakalẹ arun yii ti kọ pupọ wa ni ẹkọ rẹpẹtẹ lara eyi ti mo le sọ pe bi a ṣe n sunmọ Ọlọrun. Ẹkọ nla lo jẹ fun mi nitori pe o tun fun mi lanfaani lati mọ ẹbi mi siwaju si i. Mo dupẹ gidi lọwọ yin.
"Mo gba lati di aṣoju ẹgbẹ yii, ṣugbọn nnkan to ba ti ni i ṣe pẹlu oriṣa ni mi o le ba a yin ṣe. Mo nifẹẹ ere idaraya gidi. Awọn eeyan sọ pe ka ni ori-oke, ṣugbọn mo wo o pe kaka ki a ni ori-oke, ki lo de ta o le ni ilẹ ti a maa fi da oko. Ko si beeyan ṣe maa lo oṣu mẹta ninu oko ti ẹni naa ko ni lowo lọwọ."
No comments:
Post a Comment