WAHALA MI-IN TUN DIDE L'ONDO, AJAYI WO ILE IGBIMO ASOFIN LO KOOTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 7, 2020

WAHALA MI-IN TUN DIDE L'ONDO, AJAYI WO ILE IGBIMO ASOFIN LO KOOTU

Ona mi-in ni wahala to n sele laaarin awon oloselu n'ipinle Ondo tun gba yo bayii, n'igba ti igbakeji Gomina ipinle naa, Ogbeni Agboola Ajayi wo gbogbo ile igbimo asofin lo siwaju ile-ejo giga t'ilu Abuja.

Ki i se pe Ajayi deede wo ile igbimo naa lo sile-ejo, bi ko se lati dekun ipinu lati yo o n'ipo gege bi igbakeji gomina, eyi ti won ti bere latigba to ti f'egbe oselu APC sile lo sinu egbe oselu PDP.

Agbejoro fun Ajayi, Ogbeni I. Olatoke (SAN) lo pe ejo naa pe ile igbimo asofin. oga olopaa pata lorile-ede yii, komisanna olopaa ipinle Ondo, awon otelemuye ati olori ile igbimo asofin, Onorebu David Oleyeloogun n sise lodi s'oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI