Òní lo pé ọsẹ kan gbáko tí tirela Dangote tẹ àwọn tí kò dín ni mẹ́ta pá lójú ọ̀nà Papalanto silu Ilaro, ipinlẹ Ogun.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kí i ṣe àkọ́kọ́ rèé tí tirela Dangote yóò máa pá àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n èyí tó ṣẹlẹ̀ gbẹyin yìí ló mú káwọn aráàlú máa rawọ ẹ̀bẹ̀ sijọba àpapọ̀ atijọba ipinlẹ Ogun láti wá nnkan ṣe sí òpópónà náà.
Àwọn kan tilẹ̀ ń bẹ ìjọba láti gba ileeṣẹ Dangote láàyè láti ṣe òpópónà náà pẹ̀lú owó orí tí wọn yóò san fún bí í ọdún mélòó kan.
Kò sẹ́ni tó rí ijamba náà, tí àánú abiyamọ kò níí ṣe é nítorí tó báni lọkan jẹ pupọ.
No comments:
Post a Comment