Àdúrà làwọn ara agbegbe Oko-Erin nipinlẹ Kwara mú sẹnu fún Gómìnà wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lórí bí iṣẹ ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu ni afárá tó já lulẹ lójijì, tó sì pá àwọn èèyàn dànù laipẹ yìí.
Kọmiṣanna fún eto àkànṣe iṣẹ́, Onimọ-ẹrọ Rotimi Iliyasu lo lewaju bí iṣẹ ṣe bẹ̀rẹ̀ nibẹ fún ìgbádùn àwọn aráàlú.
Agbegbe òpópónà Taiwo n'iṣẹ náà tí bẹ̀rẹ̀, tí wọn yóò sì ṣiṣẹ náà gbà Oko-Erin/Osere títí dé Asa Dam.
No comments:
Post a Comment