Ko sẹni to ri bi iyale ile ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Ifeoma Ozougwu ṣe da pataani si ọmọ-ọdọ rẹ, ọmọ ọdun mẹwaa, Nneoma Nnadi lara yannayanna ti ko ni ṣepe abiyamọ fun un.
Adugbo Akomaeze, Thinkers Corner, ilu Ẹnugu, ipinlẹ Ẹnugu n'iṣẹlẹ naa ti waye.
Wọn ni ayọọnu (iron), irin gbigbona ni Ifeoma fi jo ọmọ naa lara nitori ti ko nifẹẹ rẹ, ti wọn si l'ọpọ igba lo maa n fi iya jẹ ọmọ naa.
Ni bayii, ọwọ ọlọpaa ti tẹ obinrin naa pẹlu ọkọ rẹ, Jude Ozougwu, ẹni ogoji ọdun ti wọn loun naa mọ nipa ẹ.
Ọmọ igba ni wọn ni Ifeoma ti lu ọmọ naa, ko da, ti wọn ni yoo tun fi ata pa nnkan ọmọkunrin ọmọ naa lasiko to ba n da seria fun un, bẹẹ ni yoo tun fi iṣo gun un ni gbogbo ara.
N'igba to n fi iroyin naa mulẹ laarọ oni Satide, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ẹnugu, Daniel
Ndukwe sọ pe awọn ara adugbo naa lo fi ẹjọ sun un n'igba ti wọn ri iwa buruku tuntun ti Ifeoma, ọlọmó mẹta naa hu.
No comments:
Post a Comment