O PARI! OZEKHOME TUN JẸRI TAKO MAGU N'IWAJU IGBIMỌ SALAMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 29, 2020

O PARI! OZEKHOME TUN JẸRI TAKO MAGU N'IWAJU IGBIMỌ SALAMI

Ko ti i daju pe alaga tẹle fun ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo kumọkumọ lorilẹ-de yii, EFCC, Ibrahim Magu ti wọn yọ danu laipẹ yii yoo bọ ninu ẹsun jibiti ti wọn fi kan an lori b'awọn kan ṣe n dide jẹri lati tako o.

L'ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana ni gbajumaja agbẹjọro kan, Oloye Mike Ozekhome (SAN) yọju siwaju igbimọ Onidajọ Ayọ Salami to n ṣe iwadii lori awọn ẹsun ti wọ fi kan Magu.

Ko din ni oriṣiriṣi ohun ẹri la gbọ pe Mike Ozekhome fi silẹ niwaju igbimọ naa, to fi mọ fọnran meji ọtọọtọ to fi n jẹri tako Magu wi pe loootọ l'awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Nibi ijokoo naa to le ni wakati meji gbako ni Ozekhome ti ṣalaye pe iṣakoso Magu gẹgẹ bi alaga fidihẹ fun ajọ EFCC ni ko bojumu, to si loo ku diẹ kaato, eyi to fi kun un wi pe ko yẹ ko jẹ ajọ EFCC ni wọn yoo ba awọn iwa ibajẹ bayii lọwọ ẹ.

Nígba to n sọrọ, agbẹjọro fun Magu, Ọgbẹni Tosin Ọjaọmọ sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ pe b'awọn eeyan ṣe n dide lati wa a jẹri tako onibara oun, wọn ko fun onibara oun naa, iyẹn Magu laaye lati farahan niwaju igbmọ naa, ko le sọ tẹnu ẹ, eyi to loo ku diẹ kaato.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI