Ọdọkunrin ẹni ọdún mẹ́rindinlọgbọn kan, Shagbada Erigga tí wá lahamọ ọlọ́pàá báyìí níbi tó ti ń jẹ ẹwa olómi ṣooroṣo lórí bo ṣe lu afẹsọna rẹ, Happiness Winifred pá nítorí tí kò gbà fún un láti bá a laṣepọ.
Laipẹ yìí ni ọga ọlọ́pàá ipinlẹ Ọ̀yọ́, Chuks Enwonwu fi ojú Erigga hàn fáwọn oniroyin, níbi tó ti sọ bí ọwọ ṣe tẹ ẹ. Agbegbe Oritokẹ, Ọjọọ n'ilu Ibadan, ipinlẹ Ọ̀yọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé.
A gbọ pé ó ti ṣe díẹ̀ tí Erigga àti Happiness tí wọn loo tí bímọ mẹta tẹ́lẹ̀ tí ń fẹ́ ara wọn, táwọn èèyàn sì mọ wọn gẹ́gẹ́ bí olólùfẹ́ méjì.
AWIKONKO gbọ pé lọ́jọ́ kọkanlelogun oṣù kẹfà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, Happiness gba láti sún sílè Erigga lọ́jọ́ náà, ṣùgbọ́n ṣe ló jẹ́ ìyàlẹ́nu pé obìnrin náà kò gbà kí Erigga bá a laṣepọ is èyí gan án ní wọn loo sá wàhálà silẹ láàárín wọn tó fi di pé wọn bẹ̀rẹ̀ sii lu ara wọn.
Ibi tí wọn tí ń já yìí là gbọ pé Happiness tí wọn ní ọmọ ọgbọn ọdún ni ti ṣubú, tó sì forí gba, lójú ẹsẹ lo tí tá tẹrí nípa.
Ṣe ni wọn ní Erigga kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ, tó fi sáré lọọ ju òkú Happiness sínú kọnga tí gbogbo àwọn èèyàn ń pọn lásìkò tí kò sẹnikẹni níta.
Ọjọ́ kẹrin lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà là gbọ pé ọkàn lára àwọn tí wọn jọ ń gbé inú ilé ṣàkíyèsí òkú èèyàn nínú kọnga náà lásìkò tó ń pọn omi lọ́wọ́, tó sì ké gbàjarè síta fáwọn èèyàn láti wá a wo nnkan abàmì nínú kọnga náà.
Báwọn èèyàn ṣe ríi ni wọn ti gba teṣan ọlọ́pàá lọ láti fi tó wọn létí. Ìgbà táwọn ọlọ́pàá de bẹ ní wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fà á yọ síta, tí wọn sì rí i pé olólùfẹ́ tó máa ń wà Erigga wá sílè ni.
Lójú ẹsẹ ni wọn ti sáré gbé gendekunrin náà, tí wọn sì gbé e lọ teṣan, níbi tó ti lọ ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́.
Erigga sọ pé ẹ̀dùn ọkàn lo jẹ foun nígbà tí Happiness kò gbà káwọn jọ laṣepọ, lẹ́yìn tó ti gba láti fi òun ṣe adé orí yàtọ̀ sí pé ó ti bímọ mẹ́ta. Ó ní lọ́jọ́ náà, ó àwọn jọ wẹ ni baluwẹ ni, t'oun sì nọwọ ibalopọ sì í, ṣùgbọ́n tí kò gbà.
Ó ní pẹ̀lú ìbínú lòun fi gba etí ẹ, tó sì ni ṣe ló fọ òun létí padà, ó níbi tija tí bẹ̀rẹ̀ nìyẹn t'oun fi bẹ̀rẹ̀ sii dá ẹṣẹ bo ó lójú, tó sì gbabẹ dero ọrun.
Bẹẹ lo sọ pé àṣìṣe lásán ni boun ṣe luu pá jẹ́ torí pé kí i ṣe ìfẹ́ ọkàn òun. Ó tún ní ẹru tó bá òun ló jẹ́ koun sáré lọ ju òkú ẹ sínú kọnga náà kì àṣírí má bá a tú lai mọ pe àṣírí yóò padà tú síta.
Bákan náà lo bẹbẹ fún ìdáríjì, ṣùgbọ́n tí ọga ọlọ́pàá tí sọ pé yóò fojú bá ilé ẹjọ láti gba ìdájọ́ tó tọ́ sì í.
Lára àwọn nǹkan tí wọn rí gbà lọ́wọ́ Erigga ni fóònù, awọtẹlẹ, roba idaabobo, kọ́kọ́rọ́ àti bàtà tó jẹ́ ti olóògbé náà.
No comments:
Post a Comment