Alaga ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede Naijria ti wọn le danu laipẹ yii, Ibrahim Magu ti sọ pe oun ko nii kawọ gbera mọ lati koju ija pada s'awọn to n sọrọ abuku s'oun.
O loun ti ṣetan lati bẹrẹ si i sọrọ sita lori awọn ẹsun ti wọn fi n kan oun, ti ko si sẹni toun fẹẹ tiju fun mọ lasiko yii.
Ọrọ Magu lo waye ninu atẹjade kan ti agbẹjọro rẹ, Wahab Shittu fi sita f'awọn oniroyin lọjọ Sannde ana. Nibẹ ni Magu ti sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun owo ileeṣẹ epo rọbi, iyẹn NNPC ti wọn l'awọn kan kojẹ, eyi ti ajọ naa gba pada.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe gbogbo ẹsun ti wọn fi n kan oun nita gbangba yii ni wọn ko gbe wa siwaju igbimọ Aarẹ lati fọrọ wa a lẹnu wo nipa awọn iṣẹ to ṣe nigba to wa nipo alaga.
O ni owo ti ko din ni N329 miliọnu naira ti iṣakoso oun gba láwọn da pada si sinu apo owo ileeṣẹ NNPC, ti awọn ọga agba nibẹ si bu ọwọ luu pe awọn ti gba owo naa.

Eyi l'awọn nnkan to wa ninu atẹjade naa:
No comments:
Post a Comment